Akẹkọọ TASUED para ẹ, nitori o kuna ninu idanwo aṣekagba

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n sọrọ aro nipa ọmọbinrin kan, Oshọkọya Deborah Ayọmikun, ẹni ti wọn lo mu majele ti wọn n pe ni Sniper, nitori o kuna ninu idanwo aṣekagba nileewe giga TASUED, Ijagun, nipinlẹ Ogun, to ti n kawe.

Ọjọruu, ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ yii, ni Ayọmikun gbe igbesẹ to ṣi n gbomi loju awọn ololufẹ rẹ naa. Ohun ti a gbọ ni pe ọmọbinrin yii ti ṣedanwo aṣekagba, o yẹ ko yege, ko si lọọ sinru ilu basiko ba to ni.

Ṣugbọn iṣẹ kan wa to ti kuna, beeyan ba si feeli iṣẹ kankan nipele aṣekagba, tọhun ko ni i pari ẹkọ ọhun lọdun naa mọ niyẹn, afi ko pada wa lọdun mi-in, ko waa tun iṣẹ to ti kuna naa ṣe, ko si yege.

Ibanujẹ aiyege, ati aini i le ba awọn ẹgbẹ rẹ yooku lọọ sinru ilu ni wọn lo mu Ayọmikun gbe majele mi-in, to si ṣe bẹẹ dagbere faye.

Aarẹ awọn akẹkọọ nileewe naa, Kọmureedi Rabiu Sọdiq, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọruu naa.

Ninu atẹjade ọhun lo ti sọ ọ di mimọ pe wọn ṣẹṣẹ fi iku Ayọmikun Deborah Oshokọya to awọn leti ni, iyẹn akẹkọọ to wa lẹka awọn to n kọ ẹkọ agba, to ṣedanwo ti ko yege, to pa ara ẹ nitori ko fẹẹ pada wa sileewe naa lati lo ọdun kan si i.

Rabiu gba awọn akẹkọọ ẹgbẹ ẹ nimọran pe bi ohun kan ba n daamu ọkan wọn, ki wọn maa ranti idi ti wọn tiẹ fi kọkọ wa sileewe naa, ti wọn n kẹkọọ,  ki wọn ma ṣe gba ẹmi ara wọn.

O tẹsiwaju pe ẹẹkan naa lẹni to gba ẹmi ara ẹ yii ku, ṣugbọn awọn eeyan to fi silẹ wa ninu ibanujẹ alailẹgbẹ, ti ko ni asiko kan ti yoo kuro lọkan wọn.

Bakan naa ni Aarẹ awọn akẹkọọ yii rọ wọn lati ma ṣe sọ ireti nu, nitori bi ẹmi ba wa, ireti n bẹ, ẹni to ku lo pari fun. O ni bi ọrọ kan ba n ka wọn laya, ki wọn wa ẹni kan sọ ọ fun, o daa ju ki wọn da ẹmi ara wọn legbodo lọ.

Leave a Reply