Akẹkọọ ti ko ba lo ibomu ko gbọdọ wọnu ọgba ileewe -Ijọba Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Pẹlu bawọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama ṣe n gbaradi lati pada sẹnu ẹkọ wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣekilọ fawọn alaṣẹ ileewe; ijọba ati aladaani, lati ma gba akẹkọọ kankan ti ko ba ti lo ibomu laaye wọnu ọgba ileewe wọn.

Bakan naa, ijọba ni ileewe yoowu ti ko ba tẹle ilana tajọ to n gbogun ti arun lorilẹ-ede Naijiria, NCDC, ati ileeṣẹ eto ilera la kalẹ fun didẹkun atankalẹ arun Covid-19 yoo fimu kata ofin.

Akọwe agba nileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, Ministry of Education and Human Capital Development, Abilekọ Kẹmi Adeọsun, lo ṣekilọ naa nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn alakooso eto ẹkọ nipinlẹ Kwara l’Ọjọbọ, Tọsidee, to waye niluu Ilọrin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin nileeṣẹ naa, Yakub Kamaldeen Aliagan, gbe sita, o ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti buwọ lu ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021, gẹgẹ bii ọjọ iwọle fun saa ikẹkọọ keji (Second term).

O ni o ti di dandan fun gbogbo ileewe patapata nipinlẹ Kwara lati tẹle awọn ilana Covid-19.

Adeọṣun ni ijọba n sa gbogbo ipa lati ri i pe arun Korona ko tan kaakiri, fun idi eyi, araalu gbọdọ ran ijọba lọwọ nipa titẹle ofin.

Ninu ọrọ rẹ, Alaga ẹgbẹ awọn olukọ nipinlẹ Kwara,

Oloye Olu Adewara, dupẹ lọwọ gomina bo ṣe gbe igbesẹ naa, paapaa ju lọ fun awọn eto idagbasoke tijọba n ṣe lẹka ẹkọ.

O ṣeleri pe awọn yoo tẹle ilana ati ofin tijọba la kalẹ.

Leave a Reply