Akeredolu ṣatilẹyin fun iwọde SARS, o tun gbe igbimọ oluwadii kalẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu naa ti ṣe bii ti awọn ẹgbẹ rẹ lawọn ipinlẹ kan pẹlu bo ṣe darapọ pẹlu awọn to n ṣe iwọde SARS niluu Akurẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Arakunrin ṣeleri fawọn olufẹhonu han ọhun lasiko ti wọn lọọ ba a nile ijọba to wa ni Alagbaka, pe ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ṣiṣẹ lori ohun ti wọn n beere fun.

Igbimọ ọhun ti adajọ-fẹyinti kan jẹ alaga rẹ lo ni yoo ṣewadii ọkan-o-jọkan iwa ibajẹ tawọn ọlọpaa SARS ti hu sawọn eeyan ipinlẹ naa sẹyin.

O ni gbogbo awọn ti ọlọpaa ti fiya jẹ tabi ti mọle lọna aitọ atawọn ti wọn ti fipa gbowo kan tabi omiran lọwọ wọn lo lẹtọọ lati wa siwaju igbimọ yii lati waa sọ ohun toju wọn ri.

Aketi ni loootọ lawọn to n ṣe iwọde ọhun sọ pe ko fi bẹẹ si wahala laarin awọn eeyan ipinlẹ Ondo atawọn SARS, sibẹ, igbesẹ to dara ju lọ ni bi ọga ọlọpaa patapata ṣe fagi le wọn.

O ni ki i ṣe awọn ọdọ nikan ni wọn n fara gba ninu iwa ipa to wa lọwọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale naa, ọpọ awọn eeyan pataki lorilẹ-ede ede yii lo wọn ni wọn ti ni iriri ohun to jọ bẹẹ lati ọwọ wọn.

Gomina ni kawọn eeyan ọhun lọọ fọkan balẹ, nitori pe abajade ohun tí awọn fẹnu ko si ninu ipade ti awọn ṣe pẹlu Aarẹ Buhari ati Igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Oṣinbajo, ni pe atunto gbọdọ waye lori iṣọwọ ṣiṣẹ awọn ọlọpaa Naijiria.

Bakan naa lo tun fi asiko naa dupẹ lọwọ wọn fun bi akitiyan wọn ṣe mu opin ba iwa ibajẹ ti awọn ọlọpaa SARS n hu lati ọjọ pipẹ.

Leave a Reply