Akeredolu ṣebura fawọn kọmiṣanna tuntun l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ṣebura fawọn kọmiṣanna tuntun mẹrinla atawọn oludamọran meje ti awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ṣayẹwo fun lọsẹ to kọja.

Ayẹyẹ ibura ọhun waye ninu gbọngan aṣa Doomu to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, niluu Akurẹ lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ, Gomina Akeredolu kọkọ ki awọn ọmọ igbimọ alabaaṣiṣẹpọ rẹ tuntun naa ku oriire fun iyansipo wọn, bakan naa lo rọ wọn lati huwa bii aṣaaju rere nibikibi ti wọn ba fi wọn si lẹyin ibura wọn.

Gomina ni oun ri i pe wọn kun oju oṣunwọn loun fi yan wọn sipo, bẹẹ ni ko ni i bojumu rara ki awọn kọmiṣanna ọhun ja ireti ti awọn eeyan ni ninu wọn kulẹ.

O ni awọn eeyan ọhun gbọdọ gbiyanju lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ti oun n dari lati mu aye ati igba rọrun fawọn araalu.

Nipari ọrọ rẹ, Arakunrin ni kawọn oṣiṣẹ ijọba lọọ fọkan balẹ, nitori pe eto ti n lọ lọwọ lati sanwo gidi fun wọn lara owo-osu tijọba jẹ wọn saaju ọjọ Keresimesi to n bọ yii.

Leave a Reply