Akeredolu ati Fayẹmi ṣabẹwo si Tinubu ni London

Jọkẹ Amọri

 Ere ni awọn eeyan kọkọ pe ọrọ naa, nigba to kọkọ gba ori ẹrọ ayelujara laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, yii kan pe Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ati ojugba rẹ lati ipinlẹ Ekiti, Dokita Fayẹmi ti wa ninu baalu to n lọ si London, wọn fẹẹ lọọ ṣe ‘ṣara balẹ’ si Asaaju ẹgbẹ APC, Oloye Bọla Tinubu.

Ohun ti ko jẹ ki awọn eeyan gba ọrọ naa gbọ ni pe wọn ni aarin awọn gomina meji yii ati Tinubu ko gun daadaa. Wọn ni awọn ọrọ oṣelu ati igbesẹ kan tawọn gomina naa n gbe lori ipo aarẹ ọdun 2023 lo n fa dukuu laarin wọn.

Ṣugbọn ba a ba n ja, bii ka ku kọ ni wọn fi ọrọ naa ṣe pẹlu bi awọn mejeeji ṣe tẹ baalu leti, ti wọn lọọ wo ọkunrin oloṣelu ti ojojo n ṣe, ṣugbọn ti ara rẹ ti n kọfẹ naa.

Ki i ṣe awọn eeyan wọnyi ni wọn yoo kọkọ ṣabẹwo si gomina Eko tẹlẹ yii.

Aarẹ Buhari paapaa bẹ Tinubu wo nigba to wa niluu London, Gomina Babajide Sanwo-Olu paapaa ti lọ. Aṣofin to n ṣoju wọn niluu Eko, Abiọdun Faleke, naa ti ṣabẹwo, bẹẹ si ni oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ APC tẹlẹ, Dokita Muhiz Banirẹ, naa ti debẹ.

ALAROYE gbọ pe awọn oloṣelu nla nla mi-in naa ti ṣabẹwo sọdọ Tinubu, ṣugbọn ti wọn ko ṣe ọrọ naa ni alariwo.

Leave a Reply