Akeredolu ba mọlẹbi awọn ti tirela tẹ pa l’Akungba Akoko kẹdun

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ba gbogbo mọlẹbi awọn to ku sinu ijamba ọkọ to waye l’Akungba Akoko lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, kẹdun lori ọfọ nla to ṣẹ wọn.

Akeredolu sọrọ ibanikẹdun yii lasiko to ṣabẹwo sibi tiṣẹlẹ naa ti waye lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

O di ẹbi awọn ijamba ọkọ to n waye leralera lagbegbe naa ru ere asapajude tawọn awakọ n sa ati iwa aika nnkan si ti wọn n hu lasiko ti wọn ba ṣakiyesi pe ọkọ awọn fẹẹ yọnu.

Arakunrin ni ki gbogbo awọn ti eeyan wọn fara gba ninu ijamba naa fọkan balẹ, nitori pe eto ti n lọ lọwọ labẹnu lati peṣe iranwọ to yẹ fun wọn.

O ni ijọba ti pinnu lati ṣawari ẹni to ni ọkọ ajagbe to paayan rẹpẹtẹ ọhun lọnakọna lati waa tan ọran ti awakọ rẹ da silẹ.

Alalẹ tilu Akungba, Ọba Sunday Ajimọ, ni ohun ti ilu n fẹ ni kijọba ba awọn sọ ọna to gba Akungba Akoko kọja di onibeji, tabi ki wọn kuku la ọna mi-in fun awọn ọkọ ajagbe lati maa gba dipo ki wọn maa rin laarin igboro ti wọn ti n fẹmi awọn eeyan ṣofo.

Nigba to n fi imọlara rẹ han lori iṣẹlẹ ọhun, ọga agba patapata fajọ ẹsọ oju popo, Ọgbẹni Bọboye Oyeyẹmi, ni ọna kan ṣoṣo tijọba fi le dena iru ijamba bẹẹ lọjọ iwaju ni ki wọn ko gbogbo ọja to wa lẹgbẹẹ oju ọna kuro lọ si ibi ti aabo yoo ti wa fun wọn.

Leave a Reply