Akeredolu di gomina Ondo lẹẹkeji

Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti kede Gomina Rotimi Akeredolu to wa lori aleefa bayii pe oun lo tun jawe olubori ninu eto idibo to waye nipinlẹ Ondo ni ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii.

Ijọba ibilẹ mẹjila ni Akeredolu ti gbegba oroke ninu mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa. Ibo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun din mẹjọ ati diẹ (292, 830) lo ni, nigba ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, ni ibo ẹgbẹrun lọna igba o din marun-un ati diẹ (195, 791).

Esi idibo yii fi han pe Akeredolu ni yoo tun tukọ ipinlẹ Ondo fun ọdun mẹrin mi-in.

Leave a Reply