Akeredolu fofin de awọn ọlọkada l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Latari ọkan-o-jọkan iwa ọdaran to n waye lemọ lemọ lati bii ọsẹ meji sẹyin nipinlẹ Ondo, Gomina Rotimi Akeredolu ti kede fífi ofin de awọn ọlọkada kaakiri ipinlẹ naa.

Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ, Donald Ọjọgo, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lorukọ gomina. O ni ẹdun ọkan nla lo jẹ fun ijọba fun bi awọn ọdaran kan ṣe n digunjale, ti wọn si tun n ji awọn eeyan gbe latari awọn ẹsọ alaabo ti ko ti i pada ṣenu isẹ wọn.

Ọjọgo ni ijọba ti fofin de iṣẹ awọn ọlọkada lẹyin aago mẹfa irọlẹ si mẹfa aarọ lojoojumọ.

Kọmisanna ọhun tun kilọ fun gbogbo awọn to n lo ọkọ onigilaasi dudu la ti ri i pe wọn gba awọn iwe aṣẹ to rọ mọ ọn ki wọn too maa wa a laarin igboro.

Awọn ofin mejeeji yii lo ni o gbọdọ fẹsẹ mulẹ bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ta a wa yii, o ni ijiya to lagbara ti wa nilẹ fun ọlọkada tabi awakọ tọwọ ba tẹ pe o ru eyikeyii ninu wọn.

O bẹ awọn ẹsọ alaabo ki wọn pada ṣenu iṣẹ aabo ti wọn n peṣe fawọn eeyan ni ẹkunrẹrẹ, bẹẹ lo tun rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba atawọn agbofinro nitori pe ọrọ aabo ki i ṣe iṣẹ ẹni kan ṣoṣo.

Leave a Reply