Akeredolu gba iwe-ẹri mo yege lọwọ ajọ eleto idibo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹsẹ o gbero  ni olu ileesẹ ajọ eleto idibo to wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ, laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii nigba ti Gomina Rotimi Akeredolu ati ẹni ti wọn jọ dije, Lucky Ayedatiwa, n gba iwe- ẹri ‘mo yege’ wọn lọdọ ajọ naa.

Gomina ti wọn tun dibo yan lẹẹkeji ọhun dupẹ lọwọ ajọ eleto idibo fun aṣeyọri ti wọn ṣe lori eto idibo to gbe e wọle lọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja.

Akeredolu tun fi ẹmi imoore rẹ han si awọn ẹsọ alaabo fun ipa takuntakun ti wọn ko lori pipeṣe aabo fawọn eeyan, leyii to mu ki ohun gbogbo lọ ni alaafia.

Gomina ọhun ṣeleri lati tẹsiwaju ninu awọn isẹ idagbasoke to n lọ lọwọ kaakiri ipinlẹ Ondo lai fi ti ọrọ oṣelu ṣe.

Leave a Reply