Akeredolu gboriyin fun ifilọlẹ gbọngan aṣa ati iṣe Yoruba ti yoo waye ni Fasiti Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi

Ni itẹsiwaju irinajo agbekalẹ pataki nni, iyẹn gbọngan aṣa ati iṣe ti International Centre for Yoruba arts and Culture (INCEYAC) fẹẹ ṣi ni Yunifasiti Ibadan lọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti gboriyin fun iṣẹ ọpọlọ naa. O ni gbogbo aye pata lo yẹ ko ti i lẹyin, nitori gbogbo eeyan ni anfaani rẹ wa fun ti wọn yoo si jere rẹ gidi.

Gomina Akeredolu sọrọ yii lọfiisi rẹ lọsẹ to kọja, lasiko ti ikọ INCEYAC ṣabẹwo si i lati ṣalaye nipa ibudo ti yoo jẹ aaye itọju nnkan iṣẹmbaye iran Yoruba, to si tun jẹ ọna ti iran Yoruba yoo fi le maa fi nnkan ajogunba wọn le iran to n bọ lẹyin lọjọ iwaju lọwọ.

Akeredolu ṣalaye fun ikọ ti Ọgbẹni Alao Adedayọ, oludasilẹ iwe iroyin ALAROYE, ko sodi lọ s’Ondo, pe eto kan to yẹ ki gbogbo aye gbaruku ti ni ohun ti wọn fẹẹ ṣe yii, eyi to jẹ ajọṣepọ laarin INCEYAC ati Yunifasiti Ibadan, ti Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti i ṣe Igbakeji aarẹ Naijiria si jẹ olufilọlẹ rẹ.

Gomina Akeredolu tẹsiwaju ninu alaye rẹ,

“Ohun teeyan gbọdọ gbaruku ti ni iṣẹ yii, ki ilọsiwaju le ba awọn ẹka yooku. O ṣe ni laaanu pe lojoojumọ ni awọn aṣa ati iṣe Yoruba n sọnu, ojuṣe gbogbo ẹni to ba si fẹ daadaa fun iran Yoruba ni lati ri i pe awọn ohun to n bọ mọ wa lọwọ yii ko ri bẹẹ mọ, iyẹn lo fi jẹ pe gbogbo wa pata lo yẹ ka ran eto yii lọwọ, ka gbaruku ti i, ka si ri i pe o fẹsẹ mulẹ fun ilọsiwaju iran wa.

Lati ile ẹnikọọkan wa ni iṣoro yii ti bẹrẹ, gbogbo wa pata si la jẹbi ẹ. Niṣe la kọ lati fi ede wa kọ awọn ọmọ wa, a ko sọ ede Yoruba si wọn, a ko jẹ ki wọn kọ nipa aṣa, iṣe atawọn nnkan iṣembaye ti Yoruba ni, eyi ko si yẹ ko ri bẹẹ mọ, ohun ta a gbọdọ fopin si ni.

Awa gomina lẹkun Guusu yii n ṣiṣẹ lori ẹ, a n gbiyanju lori ede Yoruba, nitori ẹ la ṣe n pete pe ki ede Yoruba jẹ iṣẹ kan to di dandan fawọn akẹkọọ lati maa ṣe ni kilaasi, bẹrẹ lati alakọọbẹrẹ de girama. Ọkan lara awọn ọna ti awọn ohun ta a ni ko fi ni i parun, ti ko si ni i dibajẹ ree.

Fun eyi tẹ ẹ gbe kalẹ yii, ki i ṣe pe mo maa wa nikan, ma a tun ba awọn gomina ẹgbẹ mi sọrọ lẹkun ilẹ yii. Ma a sọ fun wọn pe eto kan ta a gbọdọ darapọ mọ leyi, a gbọdọ fi atilẹyin wa han fun agbekalẹ iṣẹ ọpọlọ to fẹẹ ba wa tọju itan, ede, iṣẹ ọna, aṣa ati iṣe wa.!’’

Bẹẹ ni Akẹti, Gomina Ọdunayọ Rotimi Akeredolu, fi atilẹyin rẹ han si eto to fẹẹ ran iran Yoruba lọwọ naa, to si tun gboriyin fawọn to ronu gbe e kalẹ.

Ṣe ṣaaju ni ikọ INCEYAC to ṣabẹwo si gomina yii, Iyẹn Ọgbẹni Alao Adadayọ, agba ọjẹ onisinnima nni, Ọgbẹni Tunde  Kelani  ati Ọgbẹni Gabriel Ṣosanya, ti ṣalaye fun un pe ibudo aṣa ati iṣẹ yii yoo kun fun iwe, aṣesilẹ iṣẹ ọpọlọ loriṣiiriṣii, iṣẹ-ọna, iṣẹ-ọwọ atawọn ohun eelo tawọn to ba fẹẹ ṣiṣẹ iwadii yoo le ṣamulo rẹ.

Wọn fi kun un pe aaye kan tawọn ọmọwe, akọroyin, onkọwe, onkọtan atawọn eeyan awujọ to ni ifẹ si iwe kika ati iṣẹ iwadii yoo le lo ni. Gbogbo ohun ti wọn ba si nilo fun iṣẹ iwadii pata ni wọn yoo ba nibẹ lai si iṣoro kan.

Yatọ si eyi, Ọgbẹni Adedayọ to ṣaaju ikọ naa ṣalaye fun Gomina Akeredolu pe,

“Ibudo ẹlẹrọ igbalode ni gbọngan aṣa ati iṣẹ yii, yoo wa fun lilo gbogbo eeyan. Awọn itan atijọ ti wọn yoo ṣe bii fiimu, ti wọn yoo ṣi lawẹlawẹ ti yoo si wa nibi itọju yoo wa nibẹ pẹlu.

Bi eyi ba ti wa, yoo rọrun fawọn to n ṣiṣẹ iwadii nipa itan Yoruba lati ri ohun ti wọn ba n fẹ lasiko lai daamu kiri rara”

Gbogbo eyi ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo yoo fi lọlẹ lọjọ Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, ninu Yunifasiti Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply