Akeredolu ni ki gbogbo awọn Fulani darandaran kuro ninu igbo ọba l’Ondo laarin ọjọ meje

Jide Kazeem

Gomina Rotimi Akeredolu, ti paṣẹ fun gbogbo awọn Fulani darandaran ti wọn n ko maaluu kiri nipinlẹ Ondo lati ko ara wọn kuro ni gbogbo inu igbo to wa nipinlẹ naa laarin ọjọ meje pere.

Lori ikanni abẹyẹfo gomina ọhun lo ti fidi ẹ mulẹ pe ijọba oun ko fẹẹ ri maaluu kankan mọ ninu gbogbo igbo ti ijọba ti ya sọtọ, nitori pupọ ninu awọn to n da ẹran kiri yii, janduku ajinigbe ati afẹmiṣofo ni wọn i ṣe.

ALAROYE gbọ pe ohun to fa igbesẹ yii ni bi iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in ṣe n fojoojumọ gbilẹ si i latọwọ awọn janduku darandaran yii l’Ondo.

Akeredolu sọ pe o ṣe ni laaanu bi awọn dandaran ti wọn n ko maaluu kiri awọn inu igbo ọhun l’Ondo ṣe n fi iṣẹ darandaran boju, ṣugbọn ti wọn lawọn iwa ijanba buruku ti wọn n ṣe fun araalu atawọn dukia wọn.

O ni, “Ni bayii a ti gbe igbesẹ lati fopin si iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in ti awọn darandaran n hu kaakiri ipinlẹ Ondo, a nigbagbọ pe awọn eeyan wa yoo le ni isinmi. Maaluu ni wọn sọ pe awọn fi n jẹ oko kiri, ṣugbọn oriṣiiriṣii iwa ̀ọdaran lo kun ọwọ awọn kan ninu wọn.

“Lati fopin si i, ọjọ meje ni ijọba yii fun kaluku wọn lati kuro ninu gbogbo igbo ti ijọba ya sọtọ nipinlẹ Ondo, , bẹrẹ lati ọjọ aje, Mọnde, ọsẹ yii, a ko fẹẹ ri ọkankan ninu wọn lagbegbe yii mọ. Bẹẹ ni wọn ko gbọdọ maa ko maaluu kiri oju popo ati laarin ilu mọ. Bẹẹ nijọba ti faaye silẹ fawọn ti wọn ba si fẹẹ maa ṣiṣẹ wọn lọ nipinlẹ yii lati forukọ silẹ pẹlu ijọba.”

O fi kun un pe, “Ojuṣe ijọba ni lati pese eto aabo to yẹ, ohun ti a si ri ni pe iwa ọdaran bii ijinigbe ati ṣiṣe ẹmi awọn eeyan lofo gbọdọ wa sopin, nitori ẹ gan-an la ṣe fun awọn to n da ẹran kiri yii lọjọ meje, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ki wọn ko gbogbo maaluu wọn kuro ninu igbo to wa l’Ondo.

Leave a Reply