Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Nitori akọlu to waye ninu ṣọọsi Katoliiki Francis Mimọ niluu Ọwọ, Gomina Rotimi Akeredolu ti paṣẹ siṣeto awọn ẹrọ a-ka-aworan silẹ (CCTV) si gbogbo ibi ti ipẹjọpọ ti n waye kaakiri ipinlẹ Ondo.
Ninu atẹjade kan ti Arakunrin fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lo ti sọrọ yii, to si ni oun paṣẹ naa latari ọkan-o-jọkan ipenija eto aabo to n sẹlẹ lawọn apa ibi kan lorilẹ-ede Naijiria.
Aṣẹ yii lo ni o gbọdọ fidi mulẹ lawọn ibi ipẹjọpọ bii, ile-ijọsin (ṣọọsi ati mọṣalasi), banki, ile-itaja, ile-iwe (lati alakọọbẹrẹ titi de Fasiti), ile-ijo, ile-ọti, ile-itura, ọsibitu, ibudokọ ati ibi gbogbo tawọn eeyan ba n pejọ pọ si.
Gomina ni nibaamu pẹlu agbara tí oun ni labẹ abala kẹrindinlọgọsan-an (176) ninu iwe ofin Naijiria ni oun n paṣẹ fun gbogbo ibi tawọn eeyan ba ti n pejọ pọ si lati lati ṣeto ẹrọ a-ka-aworan silẹ, eyi ti yoo maa mojuto gbogbo awọn iṣẹlẹ to ba n waye layiika wọn.
Awọn ẹrọ wọnyi ni gomina ni o gbọdọ ni awọn ohun eelo ti yoo maa ṣe akọsilẹ awọn nnkan tabi iṣẹlẹ to ba n waye nibi ipẹjọpọ naa ki awọn ẹṣọ alaabo le ri nnkan ṣamulo nigbakuugba ti ohunkohun ba ṣẹlẹ.
O ni wọn tun gbọdọ mọ ọgba ti ko fi bẹẹ ga yi awọn ibi ipẹjọpọ ọhun ka pẹlu awọn ẹṣọ alaabo ti yoo maa mojuto bi awọn eeyan ṣe n wọle ati bi wọn ṣe n jade.
Gomina ni oun ti paṣẹ fawọn ẹsọ alaabo bii, ọlọpaa, sifu difẹnsi ati Amọtẹkun lati maa kaakiri awọn ibi ipẹjọpọ gbogbo lati rii daju pe ofin tuntun naa fidi mulẹ.
O ni alakooso tabi adari ibi ipẹjọpọ ki ipẹjọpọ to ba kuna ati tẹle aṣẹ yii yoo foju bale-ẹjọ ni ibamu pẹlu abala igba le mẹta (203) ninu iwe ofin Naijiria.