Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Arakunrin Rotimi Akeredolu to n díje lẹẹkeji sipo gomina ipinlẹ Ondo lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ti jawe olubori lawọn ijọba ibilẹ mejila ninu mejila ti wọn ṣi kede rẹ.
Gbọọrọ gbọọrọ ni gomina ọhun lu Eyitayọ Jẹgẹdẹ to n dije labẹ asia ẹgbẹ PDP ati Agboọla Ajayi to jẹ oludije fun ẹgbẹ ZLP.
Akeredolu wẹ, o tun yan kan-in-kan-in lawọn ijọba ibilẹ bii, Ariwa Ila-Oorun Akoko, Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Guusu Ila-Oorun Akoko, Guusu Iwọ-Oorun Akoko, Ilẹ-Oluji /Oke-Igbo, Idanre, Irele, Ila-Oorun Ondo, Ọsẹ, Iwọ-Oorun Ondo, Okitipupa ati Ọwọ.
Alubami ni gomina ọhun lu Dokita Olusẹgun Mimiko mọ ijọba ibilẹ rẹ ni Iwọ-Oorun Ondo, bakan naa lo tun fi ajulọ han Ikuegboju Gboluga to n dije pẹlu Jẹgẹdẹ ni ijọba ibilẹ Irele.
Jẹgẹdẹ ni tìrẹ yege lawọn ijọba ibilẹ mẹta ti i ṣe Guusu Akurẹ, Ariwa Akurẹ ati Ifẹdọrẹ, nibi ti Gboye Adegbenro to n dije pẹlu Igbakeji Gomina, Ọnarebu Agboọla Ajayi, ninu ẹgbẹ oṣelu ZLP ti wa.
Ibo ijọba ibilẹ mẹta pere, Odigbo, Ilajẹ ati Ẹsẹ-Odo nikan lo ku ti wọn n reti lasiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.