Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Ẹgbẹ APC ti Gomina Rotimi Akeredolu jẹ oludije wọn tun ti fi ẹyin Ọnarebu Agboọla Ajayi to jẹ oludije ẹgbẹ ZLP janlẹ nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, nibi ti ọkunrin ọhun ti wa.
Ibo ẹgbẹrun mẹtala àti ọrinlelọọọdunrun-un o le mẹta (13,383) ni Akeredolu ni, Jẹgẹdẹ ni ẹgbẹrun mẹrin ati ọrinlelẹgbẹta (4,680) ti Ajayi to jẹ ọmọ bibi agbegbe ọhun ni ibo ẹgbẹrun mẹrin ati ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin (4,760).