Akeredolu tun fẹyin Jẹgẹdẹ janlẹ nile-ẹjọ lẹẹkeji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to fikalẹ siluu Akurẹ tun ti fontẹ lu bi ajọ eleto idibo ṣe kede Gomina Rotimi Akeredolu gẹgẹ bii ẹni to bori ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja.

Igbimọ ẹlẹni marun-un ọhun, eyi ti Onidaajọ Theresa Orji-Abadua jẹ alaga fun ni awọn da ẹjọ ti oludije fẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, pe ta ko jijawe olubori Akeredolu nu nitori pe awọn ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ.

Gbogbo awọn adajọ maraarun ni wọn fẹnu ko lori idajọ naa, ti wọn si ni awọn fara mọ idajọ tile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu eto idibo gbe kalẹ ninu oṣu kẹrin, ọdun ta a wa yii.

Ni kete lẹyin idajọ ọhun ni Gomina Akeredolu ti fi atẹjade kan sita, ninu eyi to ti parọwa fun Jẹgẹdẹ lati pa ọrọ oṣelu ti, ki awọn si jọ fọwọsowọpọ ṣiṣẹ lori idagbasoke ipinlẹ Ondo.

Ẹgbẹ PDP ninu ọrọ ti wọn sọ nipasẹ agbẹnusọ wọn, Kenneth Peretei ni idajọ ti igbimọ ẹlẹni marun-un ọhun gbe kalẹ ṣe ajeji patapata si iwe ofin orilẹ-ede Naijiria.

O ni idajọ naa lọwọ kan eru ninu nitori pe awọn igbimọ olugbẹjọ naa ta ko ara wọn pẹlu alaye ti wọn ṣe ki wọn too gbe idajọ kalẹ.

Peretei ni igbimọ ọhun funra wọn gba pe ẹjọ ti oludije awọn pe fẹsẹ mulẹ labẹ ofin, o ni iyalẹnu lo tun jẹ nigba ti wọn tun ni awọn da awọn ẹsun naa nu nitori ailẹsẹ nilẹ.

O ni ko si ani-ani pe ile-ẹjọ to ga ju lọ ni yoo ba awọn yanju eyi to ku.

Leave a Reply