Akeredolu yan akọwe fawọn ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo

Gomina Rotimi Akeredolu ti fọwọ si yiyan awọn akọwe fun ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo lẹyin bii osu mẹfa ti wọn ti fibo gbe awọn alaga ijọba ibilẹ naa wọle.

Orukọ awọn ti gomina ọhun fọwọ si ni ibamu pẹlu atẹjade ti alaga afunsọ fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Ade Adetimẹhin, fi sita lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii ni: Fọlọrunṣọ Ọmọgẹ fun ijọba ibilẹ Ọsẹ, Pasitọ Taye Adako, Ọwọ, Adeọla Henry, Guusu Ila-Oorun Akoko, Jide Ọkẹowo fun ijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, Amuda Tairu Abiọla, Ariwa Ila-Oorun Akoko, Fatai Tiamiyu Atẹrẹ, ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Olubi Emmanuel, Ariwa Akurẹ, Gbenga Fasua, Guusu Akurẹ ati Amofin Collins Awoṣẹyẹ Stephen fun ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ.

Awọn yooku ni Amofin Smart Amọtadowa, Idanre, Adeoye Adeniyi Henry, Ìjọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, Alaaji Bisaru Oluwọle, ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, Bisi Faṣọgbọn, Ilẹ-Oliji /Oke-Igbo, Tosin Ọbayegun, Odigbo, Ikuẹjamọna Johnson, ijọba ibilẹ Okitipupa, Bayọ Ṣegede, Ilajẹ, Ọladipupọ Temenu, Irele ati Amofin Ebidaubra Ebigha Iwabi fun ijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo.

Alukoro fun ẹgbẹ APC, Alex Kalẹjaye, naa fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade mi-in pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni gomina yoo bura fun gbogbo awọn kanṣẹlọ igba ati mẹta ti wọn dibo yan ninu eto idibo ijọba ibilẹ to ti waye lati ọjọ kejilelogun, osu kẹjọ, ọdun to kọja.

Leave a Reply