Akeredolu yari: A ko ni i ko Amọtẹkun sabẹ awọn ọlọpaa laelae

 

Gomina ipinlẹ Ondo Arakunrin Rotimi Akeredolu ti sọ pe awọn gomina iẹ Yoruba ko ni i gbe ikọ Amọtẹkun wọn sabẹ awọn ọlọpaa ijọba apapọ laelae. O ni ko si ohun to kan awọn pẹlu awọn ọlọpaa ju ki awọn jọ fọwọsowọ pọ lati mu awọn ọdaran ti wọn n daamu ilu lọ. Ṣugbọn pe boya ẹni kan yoo waa wa labẹ ẹni kan yẹn, ala ti ko ni i le ṣẹ ni.

Nijẹta ni ọkan ninu awọn agbẹnusọ Aarẹ, Garba Shehu, sọ pe gbogbo ara yoowu ti awọn Amọtẹkun ba fẹẹ da, abẹ awọn ọlọpaa ijọba apapọ ni wọn yoo ti maa da a, eyi to tumọ si pe awọn ọlọpaa ni yoo maa ṣeto Amọtẹkun gbogbo.

Ṣugbọn Akeredolu to jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Yoruba ni ọrọ naa ko ni i ri bẹẹ lae, nitori ofin ti wọn fi da Amọtẹkun silẹ, ofin ijọba ipinlẹ Yoruba gbogbo ni, ki i ṣe ofin ijọba apapọ, wọn ko si le waa ja kinni naa mọ awọn lọwọ lojiji, nigba ti ko si ohun to kan wọn ninu rẹ rara.

 

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

11 comments

 1. Prince Sorinola ifaolamilekan

  Kole possible

 2. oladimeji owolabi

  beni amotekun kogbodowa labe olopa rara

 3. Ki gbogbo omo Yoruba ti akeredolu leyin,ao gbodo gba kiwon ko amotekun sabe olopa.

 4. Ala ti ko le se,SE MIYYETI ALHAH WA LABE OLOPA,ERU LO NBA IJOBA APAPO, NITORI ERO BUBURU TO WA NINU WON LATI GBALE YORUBA LONA KONA ,TI KO BA JE BE KINLOKAN IJOBA APAPO PELU ETO AABO ILE YORUBA,WON O RI NKAN SE SI PIPA AWON ALAISE LAINIDI TO NLO LOWO BAYI NI OKE OYA, ÀWON EYA FULANI TO NPA OMODE,OYUN INU, AWON ALAISE,WON NPA WON NIPAKUPA , OGUN TI WON FE GBE WO ILE YORUBA LONA TI WON WA,IDI NIYEN TI WON FI FE GBA ILE YORUBA,EYIN OMO IYA MI EMA SUN LO,ERO AWON FULANI TO NSE IJOBA APAPO LOWO LOWO KODARA RARA SI AWON EYA MIRAN LORILE EDE YI,

 5. Kaka ki kiniun se akapo ekun, onikaluku yio se ode re lototo ni

 6. Kojejebe, Yoruba efimo sokan kie ti gomina akeredolu leyin o, olorun afunwa se o

 7. Saibrahim adegbol

  Eyin asiwaju wa milee Yoruba o dowo o yin oo
  Amotekun kogbodo tun wa labe Olopa mon oo, Oodua ko ni baje ooo

 8. Adewale Adeoti Nurudeen

  Bi gbogbo wa semon wipe eiya Yoruba lokawe ju ni Ile Nigeria akoko Tito bayi ti a o fi han Tori wipe oro ofin lose koya naa kiise agidi

 9. E ma je ki won ko won po mo olopa ki won ma di idakuda

  • Nwon fe gba abodi fun Amotekun gege bi won ti gba abodi fun gbogbo awon omo ogun alaabo apapo orile ede yii, sugbon awa ogba o rara ati rara, aofe ki Amotekun kio wa labe awon olopa tabi labee ijoba apapo, laelae.

 10. Aberuagba egbeji

  Ko so ohun tokan amotekun Kan ijoba apapo

Leave a Reply

//zeechumy.com/4/4998019
%d bloggers like this: