Akeredolu yege ni wọọdu rẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu to n dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC lẹẹkeji naa yege ni wọọdu rẹ. Wọọdu karun-un, ile idibo kẹfa, lo ti dibo ni Iṣokun to wa ni Ọwọ. Ibo irinwo ati mẹtala (413) ni Akeredolu ni, nigba ti Jẹgẹdẹ to n dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo mejila. Ko si sẹni to dibo kankan fun Agbọọla ti ẹgbẹ ZLP, odo lo mu.

Leave a Reply