Akin gbe ọrẹbinrin rẹ lọ sile Kabiru, lẹyin to fipa ba a lo pọ tan ni wọn ge e si wẹwẹ l’Apomu

Florence Babaṣọla

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ Kabiru Ayedun, ẹni ọdun mọkandinlogoji, lori ẹsun pe o lẹdi apo pọ mọ ọrẹ rẹ lati pa ọmọdebinrin kan, ti wọn si kun ẹya-ara rẹ wẹlẹwẹlẹ.

A gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ni aṣiri Kabiru, ọmọbibi agboole Mọniun, niluu Ikoyi, tu, ti awọn ọlọpaa si ti n dọdẹ ọrẹ rẹ, Akin, ti wọn jọ ṣiṣẹ ibi naa bayii.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Kabiru ṣalaye pe ilu Apomu loun n gbe, iṣẹ birikila loun si n ṣe, o ni toun ba ti de latibi iṣẹ loun tun maa n lọ sidii iṣẹ ọdẹ adugbo toun n ṣe lalaalẹ nitori ọmọ ẹgbẹ OPC loun.

O ni, “O pẹ diẹ ti mo ti mọ Akin, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Clumsy tabi Alupayida, ṣugbọn n ko mọ ile to n gbe ni Ikoyi. Iṣẹ Ifa lo n ṣe, o si sọ fun mi laipẹ yii pe oun fẹẹ fi ọrẹbinrin oun kan ṣe oogun owo, o ni ti mo ba le fọwọsowọpọ pẹlu oun, oun yoo fun mi ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

“Loju ẹsẹ naa ni mo sọ fun un pe n ko ṣe, n ko si le fọwọsowọpọ pẹlu rẹ nitori mo niṣẹ mi lọwọ. Nigba to di  ọjọ Tọsidee, o gbe ọmọbinrin yii wa sọdọ mi, n ko morukọ ọmọ yẹn, n ko si mọ ibi to ti wa.

“Nigba to gbe e de, mo jade fun wọn ninu yara, lẹyin to ba a sun tan, o fọwọ fun un lọrun, o si fọwọ bo o lẹnu, emi naa wọle, mo ba a di i lẹsẹ mu titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

“Nigba to ku tan ni Akin mu ọbẹ nla kan, to bẹrẹ si i ṣa a, o ge ori rẹ, o ge atẹlẹwọ, itan, ẹsẹ ati ọyan rẹ. O tu ifun rẹ, o si ko gbogbo rẹ sinu ike nla kan.

“Awọn ti wọn n gbe layiika ile mi, ti wọn n gbọ bi Akin ṣe n ṣa ọmọ naa ni wọn lọọ sọ fawọn ọga mi, iyẹn awọn OPC. Akin ti lọ ko too di pe wọn de, bi mo ṣe ri wọn ni mo sọ pe mo ti mọ nnkan ti wọn mu mi fun.

“Mo tẹle wọn, mo si sọ bi wọn ṣe le ri Akin mu, ṣugbọn wọn ko tẹle imọran mi, iyẹn lo jẹ ki Akin sa lọ ki wọn too de ibi to wa”

Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ṣalaye pe laipẹ lọwọ yoo tẹ Akin, ati pe Kabiru yoo foju bale-ẹjọ ni kete tiwadii ba ti pari.

O waa ke si awọn obi lati mojuto awọn ọmọbinrin wọn, ki wọn mọ irin wọn, bẹẹ ni ki awọn ọdaran yẹra funpinlẹ Ọṣun nitori aṣiri wọn ko ni i bo rara.

Leave a Reply