Akinrun: Idile Gbolẹru gba kootu lọ, wọn nijọba Ọṣun fẹẹ dabaru eto yiyan ọba

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Idile ọlọmọọba Gbọlẹru, niluu Ikirun, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Ọṣun, ti fori le kootu bayii lati ka ijọba ipinlẹ Ọṣun ati awọn afọbajẹ lọwọ ko lori ipinnu wọn lati mu Akinrun tuntun latidile Ọbaara.

ALAROYE gbọ pe idile mẹta lo n jọba niluu Ikirun gẹgẹ bo ṣe wa ninu akọsilẹ. Idile Ọbaara lakọọkọ, ile Adedeji nikeji, nigba ti ile Gbolẹru jẹ ikẹta.

Idile Adedeji ni Akinrun to waja ninu oṣu keji, ọdun yii ti wa, idi niyẹn ti idile Gbolẹru ṣe fọkan balẹ pe ọdọ awọn ni ọmọ-oye yoo ti jade.

Koda, a gbọ pe awọn alakooso ijọba ibilẹ Ifẹlodun ti ṣepade pẹlu wọn, bẹẹ ni awọn eeyan ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye-jijẹ ti ba wọn ṣepade.

Afi bi ọrọ ṣe yi biri lọjọ karun-un, oṣu kọkanla, ọdun yii, nigba ti adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to kalẹ siluu Ikirun, Onidaajọ S. O. Falọla, kede pe latari gbun-gbun-gbun to wa laarin awọn ọmọ ile Gbolẹru, ki ijọba kọja si ile Ọbaara lati yan Akinrun tuntun.

Idajọ yii jẹ iyalẹnu fun awọn araalu nitori ko si ẹni to beere iru ibeere bẹẹ niwaju ile-ẹjọ, bẹẹ ni wọn n sọ pe ko si ile ọlọmọọba ti oye kan ti ki i si gbun-gbun-gbun ko too di pe wọn yoo yanju rẹ laarin ara wọn.

Nitori idi eyi ni ile Gbolẹru fi mori-le ile-ẹjọ nipasẹ awọn agbẹjọro wọn; G. A. Adeṣina, T. S. Adegboyega, S. B. Ajibade, Hasim Abioye, Olugbenga Fayẹmiwo ati Ọlasunkanmi Ladeji, sọ pe iyanjẹ patapata ni ti iru rẹ ba ṣẹlẹ.

Wọn sọ pe ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ki gbogbo nnkan ṣi duro daari na, kijọba ma ṣe gbe igbesẹ kankan lori idajọ tuntun naa, ki awọn afọbajẹ naa si dawọ duro.

Wọn ni kile-ẹjọ too le sọ pe gbun-gbun-gbun wa laarin ile ọlọmọọba, o digba tijọba ba fun wọn lanfaani lati fa ọmọ-oye kalẹ, ṣugbọn ti wọn ko le fẹnu ko lori ẹni kan.

Nigba to n sọrọ lori rẹ, Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ araalu, Funkẹ Ẹgbẹmọde, sọ pe ijọba to bọwọ fun ofin nijọba awọn ati pe ohunkohun ti ile-ẹjọ ba sọ nijọba yoo tẹle.

Leave a Reply