Akọwe ati akapo mọṣalaṣi nla dero kootu n’Ibadan, wọn ni wọn kowo janmọ-ọn jẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Elewi ibilẹ kan lo sọ ninu orin ewi rẹ kan pe “Eeyan wọn, eeyan ṣoro, ara aye, eniyan ṣoro, ẹ bẹru eeyan. Ohun to ṣẹlẹ gan-an ree ni mọsalasi Ago-Ibira Central Mosque, to wa ni Mkla, ni’badan, nigba ti ni ti i ṣe akọwe mọsalasi nla ọhun, Abdulateef Jimoh, ẹni ọdun mẹrindinlaaadota (46), ati akapo ijọ Ọlọrun naa, Abdulrahman Jimoh, gbimọpọ lati lu mọalaasi naa ni jibiti owo to jẹ ẹgbẹrun lọna  ẹgbẹta-o-le-marun-n Naira (N605,000).

Ile-ejo Majisireti to wa n’Iyaganku, niluu Ibadan, lawọn afurasi mejeeji ti wọn jẹ olugbe Agọ-Ibira, ti n kaw pọnyin rojọ bayii lori ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.

Awọn ẹsun ti wọn ká sí wọn lẹsẹ ni kootu ọhun ni pe wọn lẹdi apo pọ lati huwa jibiti. Bẹẹ ni wọn já Ọlọrun lọle, wọn jiwo ni mọalaai.

Lọọya to jẹ agbẹjọro fun ijọba lori ẹsun naa, Amofin Gbemisọla Adedeji, sọ niwaju adajọ pe niṣe lawọn olujẹjọ meji yii gbimọpọ lati lu owo mọṣalaaṣi ni ponpo.

O ṣalaye pe awọn olujẹjọ ẹsun jibiti mejeeji wọnyi lawn janmọ-ọn mọṣalaṣi nla to wa laduugbo Mọkọla, n’Ibadan yii, n ko tọrọ kọbọ ti wọn fi n ba Ọlọrun dowo pọ pamọ sí.

O ni lati ọdun 2018 lawọn olujọsin naa ti n da owo ọhun ni gbogbo ọjọ Jimọ Jimọ, bi wọn ba si ti pari isin tan,  Abdullateef ati Abdulrahman ni wọn maa ko awọn owo naa fun lati maa tọju ẹ sileefowopamọ fun anfaani mọṣalaaṣi lọjọ iwaju

Gẹgẹ bi obinrin amofin to n jẹ Adedeji yii ṣe sọ, kaka ki awọn ẹru Ọlọrun wọnyi kowo si banki fun bukaata mọṣalaaṣi, apo ara wọn ni wọn n kowo pamọ si fun bukaata ara wọn.

Amọ ṣaa o, awọn mejeeji ti ṣalaye pe awọn ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun ti wọn ka si awọn lẹsẹ naa.

Agbejoro awon afurasi yii, Sunday Adediran, waa rọ ile-ẹjọ pe lati gba beeli wọn lafoju ọdaran wo wọn rara.

Adajọ kootu naa, Onidaajọ O.A. Akande, gbẹbẹ amofin naa, o si gba beeli ọkọọkan awọn olujẹjọ wọnyi pẹlu oniduuro meji ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000).

Leave a Reply