Akpabio leku meji, o pofo: Ajọ eleto idibo lawọn ko mọ nipa ibo ṣenetọ to gbe e wọle

Adewumi Adegoke
O da bii pe gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ, to tun figba kan jẹ minisita fun ọrọ Naija Delta, Goodswill Akpabio ti leku meji bayii o, to si ti pofo lọna mejeeji. Idi ni pe gbogbo erongba rẹ lati pada sileegbimọ aṣofin agba lo ti ja si pabo bayii pẹlu bi ajọ eleto idibo ṣe sọ pe awọn ko mọ ohunkohun nipa ibo mi-in ti wọn ṣẹṣẹ di lọsẹ to kọja ti wọn ti n pariwo pe oun lo wọle.
Akpabio yii wa lara awọn to kọwe fipo wọn silẹ lati dije dupo ibo abẹlẹ lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC lasiko ibo aarẹ ọdun to n bọ. Ṣugbọn lalẹ ọjọ idibo to waye lọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni ọkunrin naa ti sọ pe oun juwọ silẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu to pada gbegba oroke, oun yoo si ṣatilẹyin fun un.
O jọ pe lẹyin to ri i pe ipo aarẹ ko bọ si i mọ lo pada sọdọ awọn eeyan rẹ, ni Alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Akwa Ibom, Ọgbẹni Stephen Ntukekpo, ba ni oun ti gba aṣẹ lati ọdọ awọn adari ẹgbẹ lati tun eto idibo abẹle agbegbe ti Akpabio ti wa ṣe, nitori awọn kudiẹ kudiẹ kan to wa nibẹ.
Eto idibo naa ni wọn ṣe ni Ọjọbọ, Tọsidee, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa yii. Lẹyin idibo naa ni wọn ni Akpabio lo wọle pẹlu ibo ọrinlenirinwo o din meji (478), nigba ti ẹni ti wọn jọ figa gbaga, Ekpo Udom, to ti kọkọ jawe olubori lasiko idibo akọkọ ni ibo mẹta pere.
Ṣugbọn ninu alaye ti Ọga ajọ eleto idibo nipinlẹ naa, Mike Igini, ṣe fun akọroyin Daily Trust lo ti ni oun ko mọ nipa eto idibo kankan to tun waye lẹyin eyi ti awọn ti di ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii. O ni eto idibo ti ọjọ yii nikan ni ajọ eleto idibo wa, ti wọn si mojuto o. Lẹyin amojuto naa ni wọn fi orukọ awọn to jawe olubori ranṣẹ si ajọ naa niluu Abuja.
Igini ni ko si wahala kankan lasiko idibo naa debii pe atundi ibo yoo waye, bẹẹ lo ni ko si ootọ ninu pe ajọ eleto idibo wa nibi idibo abẹle mi-in ti wọn ṣẹṣẹ di lọjọ kẹsan-an, oṣu yii.
Bakan naa lo ni ko si ẹni ti yoo dije dupo gomina nipinlẹ naa labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nitori bi ẹgbẹ naa ṣe pin si meji, ati wahala ti wọn n ba ara wọn fa. O fi kun un pe ajọ eleto idibo ipinlẹ naa ko mọ ohunkohun nipa eto idibo abẹle gomina ti wọn ṣe, nibi ti wọn ti sọ pe Akanimo Udofia lo jawe olubori, nitori pe awọn kọ lawọn mojuto idibo naa.

Leave a Reply