Ala ti ko le ṣẹ ni ki n dara pọ mọ ẹgbẹ APC – Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi iroyin ṣe gba ilu kan pe gomina ipinlẹ Ọyọ Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, n gbero lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP to fi ṣàtẹ̀gùn dépò gomina silẹ lati dara pọ mọ APC to jẹ ẹgbẹ oṣelu alatako ni ipinlẹ naa, gomina yii sọ pe inu oun dun pe APC n fẹ oun ninu ẹgbẹ wọn, ṣugbọn ala ti ko le ṣẹ ni ki oun dara pọ mọ wọn.

Lati ọsẹ to kọja niroyin ti n gbe e kiri pe awọn alatilẹyin Makinde ti dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu Onígbàálẹ̀, ati pe gomina yii funra rẹ ti dara pọ mọ ẹgbẹ naa labẹnu.

Wọn ní nitori pe awọn araalu ko gba ti gomina yii mọ nitori ọwọ yẹpẹrẹ to fi mu ọrọ eto aabo lo ṣe pinnu lati lọ sinu ẹgbẹ APC.

Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori ahesọ iroyin naa ninu atẹjade ti Akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Taiwo Adisa, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, lọsẹ yii, o ni kò sí ootọ kankan ninu gbogbo iroyin naa, ṣugbọn ahesọ iroyin naa kò yà oun lẹnu, awọn àṣeyọrí ti oun n ṣe lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan lo mu ki oun maa da ẹgbẹ APC lọrun.

O ṣalaye pe, “Pẹlu ofin ati ilana iṣejọba awa-ara-wa ni Gomina Makinde fi n mojuto ọrọ eto aabo ni ipinlẹ yii. O gba pe gbogbo ẹni to ba ti n huwa ọdaran pata lọta ijọba, ti oluwa rẹ yoo sì jiya to bá tọ sí i labẹ ofin lai fi ti ẹya ti iru ẹni bẹẹ ba ti wa ṣe.”

“idí tó ṣe wù awọn ẹgbẹ oṣelu alatako naa pe ki oun dara pọ mọ wọn ko ṣẹyin ọpọlọpọ aseyori ti oun ti ṣe lẹnu ọdun kan o ti oun ti dépò gomina

“Awọn APC waa ro pe nnkan to daa ju fun awọn lati ṣe bayii ni ki Gomina Makinde wa sinu ẹgbẹ awọn lati waa dupo gomina lorukọ ẹgbẹ naa. Wọn mọ pe iṣejọba rẹ yóò ṣàtúnṣe sí gbogbo nnkan ti iṣejọba ẹgbẹ oṣelu awọn ti bajẹ sẹyin, ẹgbẹ APC ni yóò sì gba ògo àṣeyọrí naa”.

Leave a Reply