Alaafin ṣabẹwo si Oluwoo, o lawọn oloṣelu lo n da wahala silẹ laarin awọn ọba Yoruba

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, ti ṣeleri pe gbogbo ipa oun loun yoo sa lati ri i daju pe iṣọkan ati igbọra ẹni ye pada saarin awọn lọbalọba ilẹ Yoruba.
Lasiko ti Ọba Adeyẹmi ṣabẹwo si Oluwoo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, laafin rẹ ni Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni kabiesi sọ pe itanra ẹni jẹ lasan ni ti ẹnikẹni ba n sọ pe iṣọkan wa laarin awọn ọba Yoruba.
O ni lati asiko Ọyọ ọjọhun (Old Oyo Empire) ni wahala naa ti bẹrẹ, oun si ti setan bayii lati ṣeto bi iṣọkan naa yoo ṣe pada. Alaafin ni ohun ibanujẹ lo jẹ pe ko si ibi kankan fun awọn lọbalọba labẹ eyi ti wọn ti le fi ohun kan ṣoṣo sọrọ lasiko wahala ifẹhonu han EndSars to waye kọja.
O waa gboṣuba fun Oluwoo fun iduroṣinṣin rẹ lai ka awọn ipenija to n koju rẹ si. O ni ogun ọdun akọkọ lẹyin toun gori itẹ awọn baba nla oun kun fun ọpọlọpọ wahala, koda, to ju eyi ti Oluwoo n koju lọ.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Oluwoo ti ilu Iwo sọ pe oun mọ riri abẹwo Ọba Adeyẹmi, o ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ọba to lapọnle nilẹ Yoruba ati orileede Naijiria.
Oluwoo ni ọrọ ati igbesẹ Alaafin pọn dandan lasiko yii ti ko si iṣọkan laarin awọn lọbalọba ilẹ Yoruba.
Lara awọn ọba to pẹlu Oluwoo ni Aagberi ti Iragberi, Akire ti Ikire Ile ati Adatan ti Aṣa.
@@@@@@@@

Leave a Reply