Alaafin gbẹsẹ le ade Ọba Ẹdu l’Ọyọọ, lo ba lọọ kan an mọgi laafin rẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Owe Yoruba to sọ pé “Ade ori la fi i m’ọba, ilẹkẹ ọrun la fi i mọ’joye” ti dowe atijọ bayii nitori ki i ṣe ọba nikan lo n dade mọ laye ode oni. Ṣugbọn Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi (Kẹta) ti fẹẹ fẹsẹ aṣa atijọ naa rinlẹ pada bayii pẹlu bo ṣe binu gba ade lori babalawo kan, Ifatokun Jayeọla Morakinyọ, o ni baba naa ko lẹtọọ lati d’ade nitori pe ki i ṣe ọba.

Nigba ti Ọba Adeyẹmi yoo tubọ foju babalawo naa ti ọpọ eeyan tun mọ si Ọba Ẹdu gbolẹ, aarin ọpọ eeyan lo ti gba ade lori ọkunrin naa nibi tonitọhun ti n ṣọdun Ifa lọwọ.

Iyẹn nikan kọ, niṣe lọba nla naa lọọ fi ade ọhun kọ igi lẹyin to ṣi i kuro lori ẹ tan. Idi igi tẹẹrẹ giga kan bayii nidii Ogun, ninu aafin Alaafin Ọyọ ti wọn si kan ade ọhun mọ lo wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii. Wọn ni Alaafin ṣe bẹẹ lati jẹ ki gbogbo awọn to ba n lọ, to n bọ, ninu aafin oun le maa ri ade ọkunrin to n tẹ oju aṣa mọlẹ naa ni.

ALAROYE gbọ pe ṣaaju lawọn eeyan kan ti kọwe ẹsun si Alaafin nipa bi Ọba Ẹdu ṣe maa n dade lasiko to ba n ṣọdun Ifa lọwọ, ti yoo si maa huwa bii ọba. Eyi lo si mu ki ọba nla ilẹ Yoruba naa lọọ ka baba yii mọ ibi to ti n ṣọdun Ifa ẹ lọdun yii laduugbo Isalẹ Ọyọ, niluu Ọyọ, to si da sẹria ọhun fun un.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, Ọba Adeyẹmi sọ pe lati le ṣafọmọ aṣa ati iṣe Yoruba loun ṣe gbe igbesẹ naa, ati lati dena iya to le koko to ṣee ṣe ki awọn araalu fi jẹ babalawo naa fun bo ṣe n pera ẹ ni nnkan ti ko jẹ, eyi to ṣee ṣe ko fa ofo ẹnmi ati dukia.

Ọ ṣalaye siwaju pe “abẹ Oloye Ifalẹyẹ Ikuṣannu ti i ṣe Oluawo ilẹ Ọyọ ni Morakinyọ wa gẹgẹ bii ọkan ninu awọn babalawo ilu Ọyọ. Wọn ti pe Morakinyọ siwaju Oluawo ṣaaju, awijare rẹ ni pe oun ko deede maa dade, ọba alade kan nilẹ Yoruba lo de oun lade.

“Njẹ ta lọba naa to fun ọ laṣẹ lati maa dade, wọn lo dahun pe Asẹyin tilu Isẹyin ni. Niwọn igba ti oun funra rẹ si ti fidi ẹ mulẹ pe oun ki i ṣọmọ Iṣẹyin, ti ko si fẹ ka le oun kuro l’Ọyọọ, o ni lati tẹle ofin ati aṣa wa l’Ọyọọ.

 

“Eyi ta a ṣe yii, a fi ṣi awọn ọba yooku loju ni, pe ki wọn yee maa gba awọn ti ki i ṣọba laaye lati maa dade, boya nitori owo tabi nitori anfani yoowu ti wọn ibaa maa ri nidii iru igbesẹ bẹẹ.

“Tẹ ẹ ba ri i ti awọn ọdọ ba n ṣi ade lori awọn babalawo, awọn Ogboni, atawọn oloriṣa gbogbo, ẹ ma ṣe da wọn lẹbi o, wọn n daabo bo aṣa ilẹ baba wọn ni”.

Leave a Reply