‘Alaafin Ọyọ, ẹ tete gba oye Mayegun ilẹ Yoruba kuro lọwọ Wasiu Ayinde o!’

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ko jọ pe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nibi ọjọọbi Ọba Fatai Akamọ, Olu Itori, nipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ni Mayegun ilẹ Yoruba, Wasiu Ayinde, ti gba gbajumọ sọrọsọrọ  l’Abẹokuta nni, Wọle Ṣorunkẹ (MC Murphy), lẹṣẹẹ lẹnu yoo lọ bẹẹ rara. Nitori titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n binu si K1, wọn ni garagara rẹ pọ ju, ko si si apẹẹrẹ Mayẹgun lara rẹ rara.

Yatọ sawọn ẹgbẹ sọrọsọrọ aladaani ta a mọ si FIBAN, ti wọn n binu nitori ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn ni Wasiu fọ lẹnu yii, ti wọn si ni ki Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, gba oye Mayẹgun to fun Wasiu pada lọwọ ẹ, awọn araalu ti wọn ko tilẹ ba MC Murphy tan paapaa n binu si K1. Wọn ni ọjọ wo ni yoo sinmi iwa jagidijagan to n hu kiri.

Ṣe eyi kọ lakọkọ ti wọn ni Mayẹgun yoo lu eeyan lode to ba ti ṣere, ninu oṣu kẹta, ọdun yii, nigba ti ọkunrin olowo Ilaro ti wọn n pe ni Dende n ṣọjọọbi ẹ niluu Eko, gadagba ni kamẹra gbe e nibi ti Wasiu Ayinde ti gba ayaworan kan lori pẹlu ẹrọ maikirofoonu  to mu dani, to fibinu le ọkunrin oluya naa kuro loju agbo, to si jẹ pe iyẹn fẹẹ ya fọto lasan ni.

Ọrọ yii naa gbalẹ gan-an nigba naa, nitori oṣu keji ti Alaafin fi Wasiu jẹ Mayẹgun lo huwa tawọn eeyan koro oju si yii, wọn si n sọ pe njẹ ọkunrin yii yoo maye kankan gun bayii!

Nigba to tun waa di ọjọ ayẹyẹ ominiria Naijiria ti i tun ṣe ọjọọbi Olu Itori, ti wọn tun ni Oluaye awọn onifuji tun gbọwọ ẹ soke, oun pẹlu meji ninu awọn ọmọ ẹyin ẹ ti wọn pe orukọ wọn ni  KC ati Gaji, ti wọn tun lu MC Murphy to n dari eto nibi ayẹyẹ naa, to bẹẹ to jẹ ẹnu ọkunrin naa fọ, niṣe lohun ti Wasiu ṣe yii tun ru ibinu ọpọ eeyan soke, ti wọn si bẹrẹ si i sọ pe nnkan mi-in ti wa ninu ọrọ ọkunrin onifuji yii, ọrọ rẹ ki i ṣe oju lasan mọ.

Ki  lohun ti Wọle Ṣorunkẹ, iyẹn MC Murphy, ṣe fun Wasiu lode ọjọọbi naa to fi di pe ọwọ iya ba a bẹẹ, ọkunrin naa sọ pe onibaara oun kan torukọ n jẹ Faṣina Ọlajide ni Wasiu ko ki, bẹẹ ni ko darukọ oun gan-an toun n dari eto pẹlu bo ṣe kọrin lọjọ naa to. O ni eyi loun ṣe mu eeyan oun naa dani, tawọn lọọ ba Wasiu pe ko tiẹ jẹ kawọn eeyan mọ pe awọn naa wa loju agbo, ṣugbọn Wasiu ko tori ẹ ki awọn naa, lawọn ba kuro loju agbo.

MC Murphy sọ pe bawọn ṣe kuro loju agbo naa ni Wasiu atawọn ọmọ ẹyin ẹ meji sọkalẹ waa ba oun nibi toun jokoo si, bi wọn ṣe bẹrẹ si i lu oun niyẹn. Sọrọsọrọ yii ṣalaye pe ọpẹlọpẹ awọn eeyan to wa nitosi ti wọn gba oun silẹ lọwọ wọn. Nigba ti wọn yoo si fi yọnda  ẹ bo ṣe wi, ete ti wu, bẹẹ ni ẹẹkẹ ẹ naa si ti bẹ lẹgbẹẹ kan.

MC Murphy fi kun alaye ẹ pe  Wasiu pada bẹ oun pe koun ma binu, ṣugbọn oun mọ-ọn-mọ fẹẹ kaye gbọ si ọrọ naa ni, nitori oun n fẹ idajọ ododo lori ẹ. Bẹẹ loun si fẹẹ ki toun jẹ ẹkọ fun Wasiu, ẹni to fẹran ko maa lu awọn eeyan nibi to ba ti ṣere, ko si maa fi wọn gba sitaa lori ọro ti ko to nnkan.

Ta a fi pari iroyin yii, Wasiu Ayinde ko ti i fi atẹjade kankan sita lori iṣẹlẹ yii, afi akọwe iroyin ẹ, Kunle Rasheed, ti wọn lo sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.

Wọn ni Kunle sọ pe bi nnkan ba tiẹ ṣẹlẹ si MC Murphy, ki i ṣe latọdọ ọga oun rara, ko sohun to jọ bẹẹ latọdọ Wasiu.

Ṣugbọn ete ati ẹrẹkẹ Murphy  to wu, eyi ti fọto rẹ ṣi wa, bẹẹ lo si jẹ pe ẹni to gbe adiẹ otoṣi gbe ti alaroye lọrọ ọhun, nitori awọn ọmọ ẹgbẹ FIBAN ti Murphy jẹ ọkan lara wọn lawọn ko ni i gba, wọn lawọn yoo fi ọrọ jagun, awọn yoo si jare.

Aarẹ FIBAN, Desmond Nwachukwu, sọ pe o ṣẹẹ n pọ ju fun Waisu, ẹni ti wọn fi jẹ Mayegun to n huwa abuku. Nwachukwu sọ pe ki Alaafin tete gba oye to fun Wasiu yii pada lo daa ju, nitori idojutuni niwa Wasiu jẹ fun iran Yoruba. O lawọn ti fọrọ yii to awọn agbofinro leti pẹlu awọn amofin, awọn yoo si duro ti i lati ri i pe idajọ ododo waye.

Leave a Reply