Alaaji ti waa fọgbọn tuuba, a ti tun dọrẹ pada

Alaaji, agbaaya, o kuku mọ bi oun ti ṣe n mu mi. Oun naa mọ pe mi o ki i ṣe ọmọ buruku. Ti mo ba sọ ohun to ṣe fun yin, yoo ya ẹyin naa lẹnu. Nigba ti Safu ti ba mi sọrọ, ti ọkan emi naa si ti balẹ lati gba ṣọọbu lọ, Safu loun fẹ ka jọ lọ nitori oun ko tun fẹ ki n binu tabi ki n lọọ ba ẹnikankan mọ ti oun ba ti jade. Emi naa fẹ bẹẹ, n ko fẹ wahala kankan. Koda, ogi ti mo ti ni mo fẹẹ ji mu tẹlẹ, niṣe ni mo ni ko rọ ọ si fulaati ka maa gbe e lọ. Ba a ṣe jade nile ni tiwa niyẹn. Ọrẹ yin, Aunti Sikira, wa nibẹ to tilẹkun mọri, ko sẹni gburoo ẹ.

Boya lo ti i pe wakati meji ti a de ṣọọbu, ko ti i ju bii aago mẹsan-an kọja diẹ lọ, n ni mo ba rẹni naa to wọle wurẹ. Lo ba di Alaaji. N o kọkọ fẹẹ ki i, ṣugbọn nigba ti Safu wa nibẹ, ki oluwa ẹ ma si waa fi apẹẹrẹ buruku lelẹ fọmọ ọlọmọ, ni mo ba ki i. Mo ni ki lo n wa, mo beere bẹẹ ṣa, abi ewo ni ka waa ka ara ẹni mọ ṣọọbu. Lo ba ni ti oun n wa nibo, ninu ṣọọbu iyawo oun, lo ba ni oun waa ba wa ṣiṣẹ ni, oun waa ṣiṣẹ owo ti mo san lẹẹkan, nitori oun mọ pe gbese yẹn ko tẹmi lọrun bi mo ṣe san an, oun si ti ṣetan lati fi ara oun di i.

Ni mo ba fọwọ lọ ọ nimu, mo ni, ‘Agbaaya ni ọ, ẹni to o ko ba lo n wa! Awa ki i gba agbalagba si iṣẹ nibi o! Awa ọmọde la wa nibi. Bi o ba jẹ o fẹẹ san gbese ti ẹ jẹ ni, iyawo rẹ alapamaṣiṣẹ alabọdo iyawo ṣọja to wa nile ni ko o lọọ ba mi pe, ko waa ṣe bọibọi fun Safu ni wakati kan, gbogbo iranu to n ṣe yẹn lo maa gbagbe pata!’ Ni Safu ba gbẹrin lọhun-un, mo n gbọ to n pariwo, ‘Emi o fẹ ọmọ ọdọ agbalagba o, ki iya kan ma waa deyin de mi nibi o!’ Ba a ṣaa ṣe sọ ọrọ di awada ti a fi n ṣere niyẹn o. Ni Alaaji ba jokoo lo loun fẹẹ jẹun.

Safu ni mo ni ko lọọ ra amala Iya Akiimu waa fun un l’IOke-ọja, igba to si ti jade lo ti n bẹ mi pe ki n ma binu, Sikira lo ko oun si wahala. Emi naa ni ko ma binu, pe mo mọ pe iyawo ẹ ni, ṣugbọn ohun to dun mi ju ni pe ko wa si ikomọ ọmọ mi, o waa jokoo sile o n muti pẹlu awọn ọrẹ ẹ. O loun fẹẹ wa, ṣugbọn bi oun ṣe n mura lọwọ ni awọn alejo ti bẹrẹ si i de, nigba ti oun fi maa mura tan, wọn ti pọ diẹ, oun o dẹ le fi wọn silẹ. Ibi ti a ti n rojọ ni Safu ti de, lo ba ni ṣe a fẹẹ maa ki ẹnu bọ ara wa lẹnu ninu ṣọọbu oun ni. Ni mo ba ni “Ẹ ma binu o, iya oniṣọọbu!’

Ko sohun to maa n jọ Alaaji loju, ṣugbọn fun igba akọkọ, mo ri i pe ajoṣe emi ati Safu jọ ọ loju pupọ ju, bẹẹ lo n yọ wa wo. Igba to ya lo ni oun fẹẹ beere ọrọ kan lọwọ mi, ni mo ba ni ko beere. O ni ṣe emi ati Safu ti mọ ara tẹlẹ ni, abi ṣe niwọnba igba ti oun fẹ ẹ yii naa ni a di tọmọ-tiya bayii. Mo ni a ko kuku mọra, morẹnikeji ni Ọlọrun fi i ṣe fun mi ni. Awọn ọmọ Sẹki ati ọkọ ẹ ko jẹ ko raaye temi mọ, n o si le ba a wi nitori ile tiẹ naa wa nibẹ, o si gbọdọ ṣe iṣe iyawo rere lọọdẹ ọkọ ẹ, ko fi han pe ile ire la ti bi oun.

Mo ni Iyawo Dele si niyẹn, ọkọ ẹ ti de si Eko, a ko ṣaa ni i sọ pe ki oniyawo ma mu iyawo ẹ sọdọ, pe bi ko ba jẹ Safu ni, n ba mọ ọn lara, ṣugbọn Ọlọrun ti ko da mi fun wahala, ti ko si da mi lemi nikan lo ran ọmọ naa si mi. Mo ni ọmọ mi ni, morẹnikeji mi ni. Ni Safu ba ta pẹẹrẹ wọle, lo kunlẹ wọọ, lo ni Ọlọrun lo da iya oun to ti ku pada foun, lo ni oun ko ni orogun o, oun o si ni iyaale o, iya oun loun ni, ọdọ mi loun si maa wa titi aye. Lemi naa ba wọ nnkan mi mọra loju Alaaji nibẹ, ni baba ba n wo bii ẹni ti ko ri wa ri.

Ko pẹ to kuro lọdọ wa nigba ti ọkọ Sẹki de. A ki i ri ewu lọsan-an, Akinfẹnwa wa mi wa ṣọọbu, lati ibo sibo, tabi lati ọjọ wo ni iru ẹ ti ṣẹlẹ. N ko tiẹ ranti rara, nitori bi iru ẹ ba ti ṣẹlẹ ri, a jẹ nigba toun ati Sẹki ṣẹṣẹ n fẹ ara wọn ni. Nigba ti mo si ri tọhun to n paaki mọto, niṣe ni mo tun garun wo o pe abi oun ni abi oun kọ. Nigba to si ti kọja sibi ti n ko ti ri i mọ, ko pẹ ti mo n gburoo Safu to n ki i nita, ṣe wọn kuku mọra daadaa, o si fẹran ẹ. Ṣe ẹni kan tiẹ wa ti ko ni i fẹran Safu to ba ba a nibi to ti n ṣiṣẹ. Lati igba ikomọ yẹn ni Akinfẹnwa ti mu un lọrẹẹ, to ni igi iṣẹ ni. Safu to jẹ gbogbo eegun ara ẹ lo fi n ṣiṣẹ, oun gan-an lariṣẹ-ma-jẹun.

Nigba to wọle lemi naa ki i daadaa, n la ba sọrọ titi, ṣugbọn a ko ri ọrọ gidi kan naa sọ. Mo ni ki wọn ra miniraasi fun un kò jẹ́, waini nkọ, ko gba, omi ti Safu ti gbe fun un naa lo n sere ẹ mu. O ni oun waa ki mi ni, nigba to si ti sọrọ diẹ lo ti dide, to ni oun kan ni ki oun ki mi naa ni. Ṣugbọn ara fu mi, mo mọ pe iru ikini bayii ki i ṣe ojulasan. Lọjọ wo ni Akinfẹnwa ki mi ni kiki iru ẹ gbẹyin. Bo ṣe ti yaa lọ ni mo ti ni ki Safu ma binu, ko ṣaa lọọ ba mi wo ọrẹ ẹ, Sẹki, nile, ko jẹ ki n mọ boya alaafia lo wa.

Mo sọ fun un pe to ba ti ri i, ko ni ko foju kan mi ni ṣọọbu, tabi ko waa ba mi nile lalẹ. Ko si pẹ lẹyin to lọ ti wọn fi de, oun ati Sẹki ni wọn jọ pada. Mo ni ki i ṣe pe mo ni ko pe e wa bayii, pe nigba to ba ṣetan ni, o ni oun naa ti fẹẹ waa ri mi ni. Ni mo ba sọ fun un pe ọkọ ẹ ti wa, o ni Safu ti sọ foun, mo ni ṣe ko si nnkan. O ni ko si nnkan, ọrọ kekere kan lawọn fa, lo ba sọ pe oun n bọ waa fi ẹjọ oun sun iya oun. Mo ni ‘ẹjọ kẹ!’, ko ma wi nnkan kan nigba to de, o ma ni oun waa ba wa ṣere ni o. Ni mo ba ni ki lo de.

Sẹki ni ko si nnkan kan, oun kan sọ pe oun ko bimọ mọ ni o, pe eyi ti oun bi yii ti to o, ki awọn feto sọmọ bibi. O ni bi ọkọ oun ṣe yari niyẹn, to ni o ku ọmọ meji ti oun fẹẹ gba lọwọ oun Sẹki, bi oun fẹ bi oun kọ, oun gbọdọ bimọ le awọn ọmọ yii dandan ni. O ni iyẹn lawọn n fa to fi ni oun n bọ waa fẹjọ oun sun. Ni mo ba rẹrin-in! Abi iru awọn ọkunrin wo ree. O dagbere pe o fẹẹ waa fẹjọ sun, nigba ti o de, o ko wi kinni kan mọ. Ọgbọn leeyan yoo fi yanju ọrọ bayii. Emi naa fẹ ki Sẹki bimọ si i, bi ko tiẹ ju ọkan lọ, ṣugbọn ko ṣee sọ bẹẹ yẹn fun lọwọ yii.

Ati pe ki lo n kan ọkọ ẹ naa loju! Ẹni to ṣẹṣẹ bimọ ti ko ti i jade ọmọ. Ṣe o ti tun fẹẹ maa ba a sun pẹlu ara tutu ni. Itiju ti ko jẹ ko le sọrọ niyẹn. Ṣugbọn emi maa pe e, ko ma ko girigiri ba ọmọ femi o, ko ma sọ ọmọ darugbo ọsan gangan mọ mi lọwọ.

Leave a Reply