Alaba yoo pẹ lẹwọn o, ọkunrin oniṣowo kan lo lu ni jibiti  l’Afao-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Yoruba bọ wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole, ṣugbọn ọjọ ṣoṣo ni ti oni nnkan, eyi lo ba ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, Anifowoṣe Alaba, mu pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe wọ ọ wa si ile-ẹjọ Majisitreeti kan niluu Ado-Ekiti, lori ẹsun jibiti lilu.

Alaba ni wọn fẹsun kan pe o lu Ọgbẹni Jamiyu Sadu ni jibiti owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (485,000), pẹlu ileri pe oun yoo ta igi fun un.

Ọdaran naa to n gbe ni agbegbe Ararọmi, ni Afao-Ekiti, ni wọn gbe wa sile-ẹjọ naa pẹlu ẹsun ẹyọ kan.

Agbefọba, Insipẹkitọ Olumide Gbamigbade, sọ pe ọdaran naa ṣẹ ẹṣẹ naa lọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni ọdun 2020, ni deede aago mẹwaa owurọ ni agbegbe Oshodi, niluu Ado-Ekiti.

Gbemigbade ni orukọ awọn yooku Alaba ti wa ninu iwe awọn ti ọlọpaa n wa, gbogbo wọn ni wọn lu jibiti naa, ti wọn si ṣe ipinnu pe wọn yoo ko igi fun Ọgbẹni Jamiyu Sadu, ti wọn si padanu ipinnu wọn lati ko igi naa silẹ ki wọn too sa lọ.

Agbefọba fi kun un pe ẹrọ igbalode ni awọn lo lati ṣawari ọkunrin yii nibi to sa pamọ si lẹyin ti oun atawọn yooku rẹ fọgbọn gba owo naa tan.

Ẹṣẹ yii ni Gbemigbade lo lodi sofin to ni i ṣe pẹlu iwa ọdaraan ti ipinlẹ Ekiti ti ọdun 2012. O rọ ile-ẹjọ lati fun oun laaye ki oun le ko awọn ẹlẹrii oun jọ, ki oun si ṣe ayẹwo to tọ lori ẹsun naa.

O ṣeleri lati ko ẹlẹrii mẹta wa si kootu.

Ṣugbọn ọdaran na ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an. Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Abiọla Gboyega, rọ kootu lati tu onibaara rẹ silẹ pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.

Adajọ F. N Ọlaiya gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira ati oniduroo meji. Lẹyin naa lo sun ẹjọ ọhun si ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Leave a Reply