Ọlawale Ajao, Ibadan
Ileeṣẹ osin adiẹ kan ti gbe gbajugbaja ileeṣẹ ounjẹ adiẹ kan, Hybrid Feeds Limited, lọ si kootu, o ni wọn fi majele sinu ounjẹ adiye.
Lati ọdun to kọja la gbọ pe ileeṣẹ ti wọn n pe ni Redi Foods ti ra ounjẹ adiẹ lọwọ ileeṣẹ Hybrid Feeds, ṣugbọn to jẹ pe kaka ki awọn adiẹ jẹ ounjẹ naa lajẹsanra, niṣe ni wọn n ku pii pii pi bi wọn ba ti jẹ ẹ.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigbẹjọ ọhun waye ni yara igbẹjọ kẹjọ tile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa ni Ring Road, n’Ibadan.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ to lẹjọ ohun ṣe sọ ni kootu,
wọn ni lẹyin ti nnkan bii ẹgbẹrun meji adiẹ ku laarin ọjọ bii meloo kan pere ti wọn jẹ ounjẹ abami naa lawọn ti ṣayẹwo, ti iwadii si fidi ẹ mulẹ pe inu ounjẹ ti wọn fi n bọ awọn adiẹ náà ni majele wa.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe loju-ẹsẹ lawọn ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ounjẹ adiẹ naa leti, sibẹ, wọn ko ṣeeṣi fun awọn lowo kankan lati fi tu awọn ninu.
Agbẹjọro olupẹjọ, Amofin Adebayọ Salau, sọ fun adajọ pe gbogbo akitiyan awọn lati ri owo gba-ma-binu lọwọ ileeṣẹ Hybrid lo ja si pabo.
O tẹsiwaju pe ninu igbẹjọ to kọkọ waye lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun yii, lawọn olujẹjọ bẹbẹ ni kootu pe kile-ẹjọ fan awọn lanfaani lati lọọ yanju ọrọ naa labẹle, ṣugbọn to jẹ pe niṣe ni wọn kan fi akoko ile-ẹjọ ṣofo lasan nitori wọn ko gbe igbesẹ lati jẹ ki ọrọ naa yanju rara.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A n beere fun miliọnu mejila ataabọ Naira (N12.5m) gẹgẹ bii owo ti onibaara mi padanu, ati mílíọ̀nù marun-un Naira gẹgẹ bii owo awọn nnkan to bajẹ nipasẹ ounjẹ onimajele yẹn. Apapọ gbogbo owo naa jẹ miliọnu mẹtadinlogun ataabọ Naira (N17.5m).
Ninu ọrọ tiẹ, Agbẹjọro olujẹjọ, Arabinrin Ṣeun Akande, sọ fun ile-ẹjọ pe olupẹjọ ati olujẹjọ ko ti i fẹnu ko lori ọna ti wọn maa gba yanju ọrọ naa laarin ara wọn.
Lẹyin naa ladajọ kootu ọhun, Onidaajọ Ishola sun igbẹjọ si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun 2022.