Alaga awọn mẹkaniiki na awọn ọmọ ẹgbẹ loruka nitori ọrọ ilẹ l’Ekoo

Monisọla Saka
Alaga mẹkaniiki tẹlẹ kan ti sọ ara ẹ di Fadeyi oloro ọsan gangan, oogun lo fi na awọn ti wọn jọ ja, n lawọn tọhun ba n wo bii ori ẹran.
Iku ti ko ba pa ni, to ba ṣi ni ni fila, ọpẹ lo yẹ ka du, bẹẹ lọrọ ri pẹlu bi idaamu ati rogbodiyan ṣe bẹ silẹ laduugbo kan ti wọn n pe ni Amule, lagbegbe Ayọbọ, nipinlẹ Eko, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un yii, nigba ti wọn ni awọn ẹgbẹ atọkọṣe ti wọn n pe ni mẹkaniiki n wọya ija lori ọrọ ilẹ.
Gẹgẹ bi akọroyin PUNCH ṣe sọ, alaga ẹgbẹ mẹkaniiki agbegbe ibẹ tẹlẹ ni wọn lo ṣe Mathew Idowu ati Sunday Olowolayemọ lọṣẹ nitori ilẹ ti wọn ti fi fun ẹlomi-in ninu ẹgbẹ wọn.
Awọn meji ti alaga tẹlẹ ọhun fọwọ ba ni wọn ni wọn o le mira, ti wọn si di ọdẹ lẹsẹkẹsẹ, eyi lawọn eeyan ri ti wọn fi sare du ẹmi wọn, ti wọn si gbe wọn digbadigba lọ sileewosan ọtọọtọ fun itọju.
Ẹni tọrọ ṣoju ẹ kan to pe ara ẹ ni Peter Funsho, ṣalaye pe, alaga ẹgbẹ ọhun to wa lori oye bayii ati awọn oloye ẹgbẹ ni wọn jọ lọ sori ilẹ naa ki wọn le yẹ ẹ wo, ki wọn si fa a le awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lọwọ.
Wọn ni niṣe ni alaga tẹlẹ ọhun ko awọn gidigannku kan waa ba wọn lori ilẹ naa, nibẹ si ni awọn mejeeji ti bẹrẹ si i fa ọrọ naa pe awọn lawọn ni ilẹ ọhun.
Funsho tẹsiwaju pe, ohun ti alaga duro le lori ni pe wọn o gbọdọ ṣiṣẹ kankan lori ilẹ ọhun tori pe oun ṣi laṣẹ lori ẹ.
Ni Idowu, to jẹ panẹbita (panel beater) ba fesi pe wọn ti ta ilẹ naa tipẹ, ati pe alaga to n sọrọ ki i ṣe alaga ẹgbẹ naa mọ.
Bi iyan jija ṣe di ija nla niyi, ti alaga atijọ ọhun si bẹrẹ si i rọjo ẹṣẹ ati ikuuku le Idowu ati Olowolayemọ to jẹ panẹbita bii tiẹ to n gbiyanju lati gbe e nija lori.
Lojiji ni wọn ni alaga tẹlẹ ọhun yọ oruka jade lapo, to si fi gba wọn, gbalaja bayii ni wọn na kalẹ ti wọn ko si le dide mọ. Loju-ẹsẹ naa lawọn mẹkaniiki ẹgbẹ wọn ti sare si wọn, wọn gbiyanju lati gbe wọn dide, ṣugbọn wọn o ri ara gbe, oju wọn ti sare rọ, wọn si la oju kalẹ lai pa a de. Wọn o le sọrọ, wọn o si rẹnu fesi gbogbo ibeere ti wọn n bi wọn.
Funsho tẹsiwaju pe ṣọọṣi ni wọn sare gbe Idowu lọ, wolii si gbadura fun un nibẹ. Ko pẹ lẹyin naa ni ara rẹ balẹ diẹ, amọ sibẹ naa, ko le sọrọ, o kan n fọwọ ṣapejuwe lasan ni. Wọn fọrọ ọhun to awọn ẹbi ẹ leti, lawọn tọhun ba ni ki wọn maa gbe e bọ niluu wọn to wa lagbegbe Ọja-Ọdan, nipinlẹ Ogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa gbọ si ọrọ naa, wọn si mu alaga tẹlẹri ọhun atawọn mi-in, amọ wọn ti pada da wọn silẹ, wọn si ti pada sinu adugbo.
Ẹni keji ti wọn tun na loogun, Olowolayemọ, naa ṣalaye pe wọn na oun naa loogun lasiko ti oun n laja.

O ni, “Ọrọ ija ilẹ yẹn ti wa nilẹ o ṣe diẹ, awọn oloye ẹgbẹ tẹlẹri o si ṣododo pẹlu rẹ.
“Lẹyin wahala to pada waa dija yii, a da alaga wa lẹkun lati ma ṣe ja mọ gẹgẹ bii ipo olori ti wọn di mu, lemi ba bọ sibẹ lati laja. Bi alaga tẹlẹri ṣe sare wọ inu ṣọọbu nitosi ibẹ niyẹn, wọn si yọ oruka jade lati fi lu emi ati Idowu, lawa mejeeji ba nalẹ. Agbegbe Ifọ, nipinlẹ Ogun, ni wọn kọkọ sare gbe mi digbadigba lọ, nitori mi o le sun, bẹẹ ni mi o le jẹun. Wọn pada waa taari mi lọ si Ọja-Ọdan, nibi ti wọn ti n tọju Idowu, to si ti n gbadun diẹdiẹ”.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni awọn mu awọn afurasi kan, ṣugbọn awọn ti da wọn silẹ lẹyin ti wọn ti gba beeli wọn.
O ni, “Awọn aṣaaju ẹgbẹ awọn mẹkaniiki atawọn tọrọ kan ti yọju si ọga ọlọpaa agọ ọhun lati yanju ọrọ naa. Ọga ọlọpaa (DPO) fara mọ ero wọn, o si gba wọn laaye lati beeli wọn.

Leave a Reply