Alaga CAN kọminu lori bi awọn ole ṣe n ji ohun eelo-orin kaakiri ṣọọṣi niluu Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Alaga ẹgbẹ awọn Onigbagbọ nipinlẹ Ọṣun, Bishop Amos Ogunrinde, ti sọ pe awọn adigunjale kan ti n lọ kaakiri ileejọsin niluu Oṣogbo, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun, to si jẹ pe awọn ohun eelo orin atawọn ẹrọ amohun-dun-gbẹmu ni wọn n ko nibẹ.

Ogunrinde ṣalaye pe ninu oṣu kẹwaa to kọja yii ni wọn bẹrẹ iwa buburu naa, ṣọọṣi mẹta ni wọn si lọ laaarin ọsẹ meji pere.

O ni biṣẹlẹ naa ṣe kọkọ ṣẹlẹ lawọn fi to awọn agbofinro leti, bi wọn si ṣe fi pampẹ ofin mu awọn kan niṣẹlẹ naa dawọ duro, ṣugbọn lẹyin ọjọ diẹ, wọn tun bẹrẹ.

Ogunrinde ṣalaye pe ẹẹmeji ni wọn tun ti lọ sileejọsin All Saints Anglican Cathedral, to wa ni Balogun Agoro, niluu Oṣogbo, gbogbo awọn ohun eelo-orin olowo iyebiye to wa nibẹ ni wọn si ji gbe lọ.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni awọn adigunjale ṣọsẹ lawọn ileejọsin mẹta ninu oṣu kẹwaa, ti awọn si ri awọn eeyan kan mu, ṣugbọn awọn alaṣẹ ijọ Anglican sọ pe awọn ko ṣẹjọ.

Ọpalọla sọ pe, “A gbọ pe wọn lọ si ṣọọsi mẹta; All Saints Church, Balogun Agoro, lọjọ karun-un, oṣu kẹwaa, Methodist Church of Living Spring, Isalẹ Aro, lọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ati Anglican Bishop Court Church, Youth Chapel, Isalẹ Aro, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa ọdun yii.

“A mu eeyan mẹrin lori ti All Saints Church, ṣugbọn wọn sọ pe ka fi wọn silẹ nitori awọn ko fẹẹ ṣẹjọ. A ko ri ẹnikankan mu lori ti Methodist Church, awọn ọlọdẹ meji la mu lori ti ṣọọsi kẹta, ṣugbọn awọn alakooso ijọ ni ka ni suuru ko too di pe a maa gbe wọn lọ si kootu.

‘’Niwọn igba to si jẹ pe o niye ọjọ ti a fi le fi afurasi sakolo wa, a ni lati tu wọn silẹ. O ṣe ni laaanu pe asiko iwọde EndSars ni gbogbo iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, to jẹ pe inu ile lawọn eeyan wa, ṣugbọn ohun gbogbo ti pada bọ sipo bayii.

 

 

Leave a Reply