Faith Adebọla, Eko
Igbakeji Aarẹ orileede wa, to tun jẹ ondije fun ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti sọ pe afi kawọn ọmọ Naijiria gbe awawi ati aroye ju sẹgbẹẹ kan bayii, ohun to ṣe koko ju lọ ni bi a ṣe maa yan olori to dara ju laarin gbogbo awọn to fẹẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, tori a o gbọdọ ṣe ohunkohun to dinku si yiyan olori to dara ju lọ fun Naijiria.
Ọṣinbajo sọrọ yii lasiko abẹwo ati ifikun-lukun rẹ pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ APC nipinlẹ Akwa Ibom, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ta a wa yii.
Akwa Ibom nipinlẹ kẹrindinlogun ti Ọṣinbajo yoo ṣabẹwo si lati ba awọn aṣoju sọrọ lori erongba rẹ lati dije funpo aarẹ, ati lati wa awọn alatilẹyin ti yoo jẹ ki ifa fọre fun un lasiko idibo abẹle ti wọn yoo fi yan ọmo oye lẹgbẹ APC nipari oṣu yii.
Ọṣinbajo ni ko si idi meji toun fi fẹẹ jẹ aarẹ ju pe o wu oun lati lo iriri toun ni, gbogbo okun, ọgbọn ati imọ oun lati tun Naijiria ṣe lọ. O ni eto idibo 2023 yii ṣe pataki, o ṣe koko fun iran tiwa, ati iran to n bọ lorileede yii.
“O da mi loju pe ti Ọlọrun ba ran mi lọwọ, tẹ ẹ ba fun mi lanfaani lati ṣe iṣẹ yii, gbogbo ohun ti mo ba le ṣe pata ni ma a ṣe. Lagbara Ọlọrun, mo gbagbọ pe orileede yii maa dara, ọkọọkan wa la maa ri iyatọ pe patako ko jọ paali.
“Ohun ti mo n sọ fẹyin aṣoju ati gbogbo ọmọ Naijiria ni pe kẹẹ darapọ mọ mi, ka jọ gbe orileede yii goke agba, ka jọ tun un ṣe. Mo n fi ipinnu mi han pe orileede yii maa dagba soke gẹgẹ bawọn orileede ọlaju lagbaye ṣe dagba soke, a si maa jẹ ko yara dagba soke ni, bii tawọn yooku.”
Bi baaluu Ọṣinbajo ṣe n balẹ si papakọ ofurufu wọn ni Gomina ipinlẹ naa, Emmanuel Udom, ati Igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Akwa Ibom, Obong Nsima Ekere, Sẹnetọ Ita Enang ati awọn eeyan pataki ti lọọ pade rẹ, ti wọn si yẹ ẹ si. Ọṣinbajo tun ṣabẹwo si awọn ọba alaye, awọn baalẹ atawọn oloye pataki pataki nipinlẹ ọhun.
Ninu ifesipada rẹ, Alaga igbimọ awọn lọbalọba nipinlẹ Akwa Ibom, Alayeluwa Ọmọwe Solomon Etuk, sọ fun Igbakeji Aarẹ pe “A ti mọ ẹ daadaa tẹlẹ, pe eeyan alaafia to nifẹẹ, to si n wa iṣọkan orileede yii ni ẹ. Bẹẹ ni ko o maa jẹ lọ. Gbogbo ohunkohun to o ba dawọ le, Ọlọrun Olodumare yoo ṣilẹkun aṣeyọri ati aṣeyege fun ọ, tori to o ba ṣaṣeyọri, Naijiria lo ṣaṣeyọri yẹn, to o ba ṣaṣeyege, Akwa Ibom lo ṣaṣeyege yẹn. Ọlọrun aa wa pẹlu ẹ, yoo si fun ọ nigboya lati ṣaṣeyọri.”
Bẹẹ lọba alaye naa wure fun Ọṣinbajo.