Alagba Tunde Kelani fẹẹ gbe fiimu igbesi aye Ayinla Ọmọwura ati ilu Ẹgba jade

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

O to ọjọ mẹta kan tawọn eeyan ti gburoo Alagba Tunde Kelani ati ileeṣẹ Mainframe,Opomulero.

Ṣugbọn ni bayii, itan nipa igbesi aye Oloogbe Ayinla Ọmọwura ati ilu Ẹgba lapapọ ni wọn fẹẹ gbe jade.

Lọjọ Ẹti to kọja yii ni Alagba Kelani ba AKEDE AGBAYE sọrọ, wọn ni

‘‘Orin ti Ayinla n kọ nigba aye ẹ yatọ, ọlọpọlọ pipe ni, ṣugbọn o jọ pe a ti fẹẹ maa gbagbe ẹ, paapaa iru orin apala to kọ. Eyi lo fa a ta a fi jade lasiko yii lati da ogo ilẹ Yoruba pada, ati ilu Ẹgba paapaa.

‘’Fiimu ta a fẹẹ ṣe yii da lori igba to ku oṣu mẹfa pere ti Ayinla maa ku. O ṣoro lati ri fidio Ayinla, a o ri i ri ninu fidio, ṣugbọn awọn nnkan to jẹ mọ ọn pata ni iṣẹ yii maa gbe jade.

‘’Iṣẹ ti a n ya yii yatọ si gbogbo eyi ti mo ti n ṣe tẹlẹ, ohun to wa nibẹ kọja ọrọ Ayinla funra ẹ, o ni i ṣe pẹlu ilu Abẹokuta patapata. Idakeji Ayinla Ọmọwura tawọn eeyan ko mọ la gbe jade ninu iṣẹ yii, bo ṣe logba pẹlu iyawo ẹ to jẹ aayo,Tawakalitu Owonikoko,faaji to ṣe ati bẹẹ bẹẹ lọ titi to fi ku’

Nipa igba ti iṣẹ yii maa jade, baba naa ni ko ni i pẹ rara.

Leave a Reply