Alainitẹẹlọrun ati alaṣeju ni Agboọla Ajayi -Kennedy

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbakeji Gomina Ondo, Agboọla Ajayi, ti tun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, o ti lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ ZLP gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n sọ pe yoo ṣe.

Ninu atẹjade kan ti Ajayi fi sita nipasẹ Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Allen Ṣoworẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP fun bi wọn ṣe gba a tọwọ tẹsẹ lasiko to n darapọ mọ wọn lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020.

O ni idi ti oun fi gbe igbesẹ naa ko ṣẹyin ati mu idagbasoke ati itẹsiwaju ti ko lẹgbẹ ba ipinlẹ Ondo ninu erongba oun lati dije dupo gomina ninu eto idibo to n bọ.

Ọnarebu Ajayi ni lẹta ikọwe fi ẹgbẹ silẹ oun ti tẹ alaga ẹgbẹ PDP ni Wọọdu keji Apọi, nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, lọwọ lati aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹjọ, ọdun ta a wa yii.

Alukoro ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo, Kennedy Ikantu Peretei, ni lẹta ti igbakeji gomina ọhun kọ ko ti i tẹ awọn lọwọ. O ni bo tilẹ jẹ pe ori ẹrọ ayelujara lawọn ti n ka lẹta ti Ọnarebu Ajayi kọ, sibẹ, tọkan tọkan lawọn fi yọnda rẹ ko maa ba tirẹ lọ.

Kennedy ni ọpọlọpọ oore-ọfẹ lawọn aṣaaju ẹgbẹ fun ọkunrin naa latigba to ti wa lọdọ awọn, ṣugbọn iwa ainitẹẹlọrun ati aṣeju to n hu jẹ ko ṣi awọn anfaani wọnyi lo.

Alukoro ọhun ni pẹsẹ lọkan awọn balẹ nitori pe o da awọn loju pe kikuro Ajayi ko ni i di aṣeyọri ẹgbẹ PDP lọwọ ninu eto idibo to n bọ.

Leave a Reply