Adewale Adeoye
Ileejọ Majisireeti kan n’Iyaganku, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ni akẹkọọ kan, David Chimezie, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), kan ti lọọ kawọ pọnyin rojọ nipa ohun to mọ lori bi ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (N700,000) Naira, owo ele kan ti ẹgbọn rẹ, Abilekọ Chioma Onyegbula, lọọ gba lọdọ awọn ẹgbẹ alájẹ-másùn ṣe poora nibi to gbe e si.
Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Ẹlẹyẹle, niluu Ibadan, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2022.
Ninu alaye ti Olupẹjọ, Insipẹkitọ Olufẹmi Omilana, ṣe niwaju adajọ ile-ejọ naa lo ti sọ pe Abilekọ Chioma lo lọọ ya ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (700,000), owo ele, bo ṣe gbe owo naa sinu ile ni aburo rẹ, David Chimezie, ti ji i gbe sa lọ, ti ko si le ṣalaye koko ohun to fowo ọhun ṣe fun ẹgbọn rẹ. O fi kun un pe gbogbo ẹri lo fi han pe ọmọkunrin naa lo ji owo yii.
Iwa to hu yii ni agbefọba ni o lodi sofin iwa ọdaran ti ipinle naa n lo, o si ni ijiya labẹ ofin.
Nigba ti wọn ka esun naa si David leti, o loun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun pẹlu alaye.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ kootu naa, Onidaajọ Munirat Giwa-Babalọla, gba beeli afurasi ọdaran yii pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (N100,000), ati oniduuro meji ọtọọtọ ti wọn lohun ti wọn fi le duro iyẹn bi David ba sa lọ kọjọ igbẹjọ rẹ too waye. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa si ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii.