Alani Akinrinade paapaa ti tun kilọ fun Buhari o

Olori awọn ṣọja patapata nilẹ yii nigba kan, Ọgagun-agba Alani Akinrinade, sọ pe inu oun ko dun rara si ohun to n lọ labẹ ijọba Buhari yii, nitori bo ba n lọ bayii, afaimọ ko ma di pe ko ni i si ibi ti wọn n pe ni orilẹ-ede Nairjiria mo, awọn ọmo Nairjia paapaa ko si ni ni orilẹ-ede kankan, wọn yoo kan di alarinkiri lasan ni. Akinrinade ni ọro naa ko ironu gidi ba oun, nitori ẹni ti oun ro pe oun mọ daadaa ni Buhari.

Ni Oṣogbo, nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe fun olori awọn ṣọja pata, Ọgagun Tukur Buratai, to bẹ ipinlẹ Ọṣun wo ni Akinrinade ti n sọrọ yii ni alẹ Ọjo Aje, Mọnde, ọsẹ yii. O ni inu oun dun lati lo akoko naa lati fi ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari, ko le mọ ohun to n lọ laarin ilu gan-an, iyẹn bo ba ṣe pe ko gbọ tẹlẹ, tabi ti ko rẹni sọ fun un.

Akinrinade to di olori fun awọn ọga ọmọ-ogun gbogbo ni Naijiria ko too fẹyin ti ninu iṣẹ ọhun ni 1981 sọ pe awọn ọrọ ti oun n gbọ nipa Buhari wọnyi ko daa. Akọkọ ni ti pe ẹlẹyamẹya eeyan kan to fẹẹ gba ijọba Naijiria fawọn Hausa ni. Ẹẹkeji ni ti pe inu rẹ n dun si bi awọn Fulani onimaalu ti n paayan kiri, ti wọn n jiiyan gbe, nitori pe awọn ẹya rẹ ni wọn, nitori ẹ ni ko si ṣe ṣi wọn lọwọ. Ẹẹkẹta ni tawọn Boko Haram to fi silẹ ti wọn n ṣe gbogbo aṣemaṣe to wu wọn kiri. Ẹẹkẹrin si ni ti pe to ba yọ Yoruba tabi Ibo niṣẹ, ọmọ Hausa tabi Fulani ni yoo fi sibẹ, to si n gbe gbogbo ipo ppataki ninu ijọba Naijiria le awọn eeyan naa lọwọ. Akinrinade ni gbogbo ohun ti araalu n sọ nipa Buhari ti oun n feti ara oun gbọ niyi, awọn ohun to si n ṣẹlẹ laarin ilu fi han pe o fẹẹ jọ pe bi kinni ọhun ti ri ni wọn n sọ.

Ọga awọn ṣọja naa ni ohun to n ṣẹle yii ko daa, ko tilẹ daa rara, nitori ohun to le ko ba gbogbo Naijiria ni. Nibẹ lo ti ṣe kilọkilọ fun Buhari pe bi ko ba tete wa nnkan kan ṣe si awọn ọrọ yii, orilẹ-ede yii le fọ mọ ọn lori, ti yoo si tuka loju gbogbo wa. Akinriade ni Buhari gbọdọ dide, ko sọ fun gbogbo Naijiria pe aṣaaju wọn loun, oun ko si si fun ẹya kan, bẹẹ ni oun ki i ṣe ẹlẹyamẹya. O ni ki i ṣe ẹnu  lasan ni yoo fi sọ bẹẹ o, iwa rẹ ni yoo sọ eyi to pọ ju ninu ọrọ to wa nilẹ yii, nitori ohun to ba ṣe lawọn eeyan yoo ri, ti wọn yoo si maa sọ.

Leave a Reply