Ale iyawo gun ọkọ lọbẹ pa l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Daniel Udoh lọkunrin yii, iṣẹ awakọ ero lo n ṣe. Ọbẹ to fi gun ọkọ obinrin kan ti wọn lo n yan lale pa lọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, l’Ọta, nipinlẹ Ogun, lo wa lọwọ rẹ yii.

Teṣan ọlọpaa Onipaanu to wa l’Ọta lo gba ipe, ‘ẹ gba wa’ lọjọ naa, nigba ti wọn ni Daniel ti fi ọbẹ gun ọkunrin kan torukọ tiẹ n jẹ  Emaka Umonko pa.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bi alaye awọn ọlọpaa ni pe Umonko to doloogbe yii ti n fura si Daniel pe o n yan iyawo oun lale tipẹ, o si to ọjọ mẹta to ti n ṣọ wọn.

Lọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun yii, Umonko to n ṣiṣẹ jorin-jorin, ko Daniel, ẹni ọdun mejidinlogoji ( 38) loju, o ni o n yan iyawo oun lale.

Ohun to fa ija laarin awọn ọkunrin meji naa ree, ija to lagbara gan-an ni wọn pe e paapaa.

Nibi ti wọn ti n lu ara wọn naa ni Daniel ti fa ọbẹ yọ, o si bẹrẹ si i fi gun Umonko lẹyin ati aya, wọn lo gun un yankan-yankan ni, iyẹn lo mu ọkọ iyawo naa ṣubu lulẹ, ti ẹjẹ si n da lara rẹ pẹlu.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ lọrọ di ti ọlọpaa, wọn mu Daniel Udoh to gun un lọbẹ lọ si teṣan, wọn si mu ọbẹ to fi gun un dani gẹgẹ bii ẹri. Wọn sare gbe Umonko lọ sọsibitu jẹnẹra Ọta, Dokita ni ẹpa o boro mọ, ọkunrin naa ti ku.

Bayii ni wọn gbe oku ọkọ iyawo wọ mọṣuari Ifọ lọ fun ayẹwo, wọn si fi ẹni to gun un pa sẹyin gbaga lẹka to n gbọ ẹsun ipaniyan.

Wọn ko ni i pẹẹ gbe Daniel Udoh to paayan naa lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Leave a Reply