Ale ku mọ Ṣẹgun labẹ, lo ba ju oku ẹ si titi, ọlọpaa ti mu un l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọdọ ọlọpaa ni ọkunrin yii, Ṣẹgun Taiwo, ẹni ọdun mejidinlogoji ( 48) wa bayii latari oku ale e to lọọ ju ṣebaa ọna, lagbegbe kan ti wọn n pe ni Aro, l’Abẹokuta.

Awọn agbofinro ni awọn kan ni wọn lọọ fi to wọn leti ni teṣan Lafẹnwa, l’Abẹokuta, pe obinrin kan wa ni titi, awọn agbofinro si bẹrẹ iwadii lori rẹ lọwọ kan.

Ninu iwadii wọn ni wọn ti mọ pe Abimbọla Oluṣọla lobinrin naa n jẹ, ati pe ẹni aadọta ọdun (50 years) ni. Itẹsiwaju iwadii ni wọn fi mọ pe ale ni obinrin yii jẹ si Ṣẹgun Taiwo to n ṣiṣẹ alapata, wọn si ṣewadii ọkunrin naa, wọn ri i pe Ọbada Oko lo n gbe, l’Abẹokuta.

Nigba ti wọn kọkọ mu un, Ṣẹgun loun ko mọ obinrin naa ri, oun ko si mọ nipa oju titi ti oku ẹ wa. Ṣugbọn nigba tawọn agbofinro fi awọn ẹri kan han an, eyi to fi han pe o ni nnkan an ṣe pẹlu oloogbe naa, baba yii ko ri ọgbọn mi-in da mọ, nigba naa lo si jẹwọ pe ale oun ni obinrin naa i ṣe.

Ṣẹgun Taiwo sọ fun wọn pe ọdun to kọja loun ati Oluṣọla to doloogbe yii bẹrẹ si i yan ara awọn lale. O ni lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa to pari yii loun pe e wa sile oun pe kawọn jọ sun mọju, nitori iyawo oun ko si nile.

O ni oloogbe naa wa, awọn si jọ ba ara awọn ṣere ifẹ. Ṣugbọn nigba to di nnkan bii aago mẹta oru lo bẹrẹ si i fi apẹẹrẹ aiyaara han, koun si too le ṣe ohunkohun lati ran an lọwọ, niṣe lo ku patapata.

Ọgbẹni Ṣẹgun sọ pe bo ṣe ku naa loun gbe e sinu mọto oun, toun si lọọ ju oku rẹ silẹ lagbegbe Aro, loun ba pada sile bii pe kinni kan ko ṣe.

Njẹ ki lo de to fi lọọ ju oku ale rẹ naa si titi bẹẹ, ọkunrin naa sọ pe ẹru ofin lo ba oun.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, gboriyin fawọn ọlọpaa to ṣiṣẹ akin ati iwadii yii. O rọ awọn araalu pe ki wọn maa sọ ibi ti wọn ba n lọ fawọn eeyan wọn. O si ni ki wọn tete gbe Ṣẹgun Taiwo lọ sẹka si kootu lati jẹjọ.

Leave a Reply