Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bo tilẹ jẹ pe wọn to ọgọta (60) niye ti wọn dihamọra ogun wọ Abule Idiagbọn, nijọba ibilẹ Ado-Odo-Ọta, nipinlẹ Ogun, ti wọn ni wọn fẹẹ fipa gba ilẹ awọn eeyan naa lọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla yii, awọn meji yii, Ọlaolu Fashina; ẹni ọdun mejidinlọgọta (56) ati Akinshọla Oluwasanmi; ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46) nikan lọwọ ọlọpaa ba.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita ṣalaye pe awọn kan ni wọn ta teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, lolobo, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa, pe niṣe lawọn ajagungbalẹ to to ọgọta ya wọ abule pẹlu nnkan ija gbogbo, ti wọn si n daamu agbegbe naa, wọn ni ọkada rẹpẹtẹ ni wọn gbe wa.
Nigba tawọn ọlọpaa debẹ, awọn janduku naa ṣina ibọn bolẹ, wọn bẹrẹ si i yinbọn sawọn ọlọpaa ki wọn le rọna sa lọ gẹgẹ bi alukoro wọn ṣe wi.
Bi wọn ti n yinbọn ọhun lawọn agbofinro naa n le wọn, bẹẹ lawọn araalu ti wọn waa kogun ja naa kun ọlọpaa lọwọ, nigbẹyin, wọn ri awọn meji yii mu, wọn si fọwọ ofin mu wọn.
Ọta ibọn meji ti wọn ko ti i yin, pẹlu ọkada Bajaj ti nọmba ẹ jẹ TTD 472 VN lawọn ọlọpaa gba lọwọ awọn meji tọwọ ba yii.
Ọga ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, paṣẹ pe ki wọn wa awọn to sa lọ naa ri, ki wọn ko awọn tọwọ ba yii lọ sẹka iwadii to lagbara, ti yoo ṣatọna bi wọn yoo ṣe ri awọn to sa lọ mu. Bẹẹ lo kilọ fawọn janduku eeyan lati rin jinna sipinlẹ Ogun, nitori ikoko o ni i gba ẹyin, ko tun gba ṣọṣọ.