Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Iku oro lo pa baba ẹni aadọta ọdun (50) kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Akinyẹmi Wahab Alani, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹwaa yii. Ọmọdekunrin tọjọ ori tiẹ ko ju mẹẹẹdọgbọn lọ (25), iyẹn Bisi Ọmọniyi, lo ṣa a ladaa pa nitori Kafayat Sakariyau, nile obinrin ọhun to wa ni Ajilete, Owode-Ẹgbado, nipinlẹ Ogun.
Ọrẹbinrin Bisi to ṣaayan pa ni Kafayat Sakariyau ti Alani tori ẹ ku yii.
Alaye ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, ṣe nipa iṣẹlẹ yii ni pe awọn kan ni wọn pe teṣan Owode-Ẹgbado, ti wọn ni ẹnikan ti ṣaayan ladaa yanna-yanna o.
Nigba tawọn ọlọpaa debẹ ni wọn ri ohun to ṣẹlẹ, wọn sare gbe ẹni ti wọn ṣa ladaa lọ sọsibitu, ṣugbọn dokita ni o ti ku, ni wọn ba mu Bisi to ṣa ọkunrin naa pa.
Ninu iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti mọ pe yara Kafaya ni Alani ti Bisi ṣa pa wa lọjọ naa, o fẹẹ sun lọdọ obinrin naa mọju ni, nitori ọrẹbinrin rẹ ni.
Bi Alani ti inagijẹ n jẹ Ajilọpọn ṣe wa ni yara Kafaya ni Bisi toun naa jẹ ololufẹ rẹ naa tun de, koda, lati ibi kan ti wọn n pe ni Ibasa, l’Oke-Ọdan, ni Bisi ti wa si Owode-Ẹgbado lati waa lo opin ọsẹ ọjọ Jimọ naa lọdọ Kafaya.
Ṣugbọn nigba to de to ba ilẹkun ni titi, ara fu u. O kan ilẹkun naa titi, Kafaya ko ṣilẹkun nitori Alani to wa ni yara pẹlu ẹ, bi inu ṣe bi Bisi Ọmọniyi to wa nita niyẹn, lo ba ja ilẹkun wọlẹ.
Bo ti wọle to ba ọkunrin mi-in nipo ifura pẹlu ololufẹ rẹ, ija bẹ silẹ laarin oun ati Alani to n ṣe bii ọkọ iyawo. Nigba naa ni ọmọ ti ko ju ẹgbẹ ọmọ Alani lọ ki ada kan mọlẹ ninu yara naa, o si fi ṣa Alani yanna yanna, ni wahala ba bẹ silẹ gidi, nitori Alani ko ye e, o gbabẹ ku ni.
Kafaya ti wahala tori ẹ ṣẹlẹ ti sa lọ ni tiẹ, nigba to ti ri ibi ti rogbodiyan naa n lọ. Awọn ọlọpaa mu Bisi Ọmọniyi tẹ ẹ n wo yii, wọn si ti fi i ranṣẹ sibi tawọn apaayan n wa.