Ali ti dero ahamọ n’Ilọrin, baba ati iyawo rẹ lo fẹẹ bẹ lori

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọmọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Alli Hassan, nile-ẹjọ Magistreeti ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti ni ki wọn fi sahaamọ bayii fẹsun pe o n dunkooko mọ baba to bi i lọmọ, Hassan Auta, ati iyawo rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa lo wọ Ali lọ siwaju ile-ẹjọ fẹsun pe o yọ ada, to si n halẹ pe oun maa pa baba oun nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe Ali pẹẹ wọle lalẹ ọjọ naa, o si ti mu ọti amupara, lo ba mu ada, lo wọ yara iyawo rẹ lọ, o ni kiyẹn ko ẹru rẹ, ko jade ninu ile oun tabi ki oun bẹ ẹ lori. Bakan naa lo tun lọ si yara baba rẹ, to si ni oun yoo pa baba naa dandan ni. Eyi lo mu ki awọn araadugbo da si ọrọ naa.
Agbefọba, Issa Abubakar, rọ ile-ẹjọ lati fi afurasi ọdaran naa sahaamọ tori pe iwa ọdaran lo hu.
Adajọ kootu naa, Abiọla Agbetọla Issa, paṣẹ ki wọn fi Ali sahaamọ titi di ọjọ ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ti igbẹjọ mi-in yoo waye.

Leave a Reply