Amaechi ki Tinubu ku oriire, o ṣeleri atilẹyin fun un

Jọkẹ Amọle

Minisita feto irinna ọkọ tẹlẹ to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Rivers, Rotimi Amaechi, ti ki Aṣiwaju Bọla Tinubu ku oriire bo ṣe yege ninu ibo abẹle APC to kọja yii lati dupo aarẹ ẹgbẹ naa, bẹẹ lo ṣeleri atilẹyin fun un lasiko idibo ọdun 2023.
Ninu iwe kan to kọ lati fi ki i ku oriire lo ti ni ‘Mo ki ọ ku oriire fun aṣeyege ti o tọ si ọ ti o ṣe lasiko idibo abẹle APC to waye ni ọjọ keje, oṣu Kẹfa yii, ireti mi ni pe wa a jawe olubori bi o ṣe n palẹmọ fun eto idibo naa ti yoo waye ni ọdun to n bọ.
‘Bi o ṣe bẹrẹ eto irinajo to lapẹẹrẹ yii, mo n fi idaniloju mi han si atilẹyin ati aṣeyọri rẹ ninu eto idibo ọdun to n bọ naa. Bẹẹ ni mo si n foju sọna fun awọn ibi ti mo ba ti le ran ọ lọwọ, ki a le jọ gbe ọkọ Naijiria de ebute ogo.
Tẹ o ba gbagbe, Amaechi naa wa lara awọn to dije dupo aarẹ lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye ni ọjọ Keje, oṣu yii, ipo keji lo mu ninu ibo abẹle naa.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: