Amaechi ti juwọ silẹ: Tinubu ati Yẹmi Ọṣinbajo ni yoo koju ara wọn bayii

Jọkẹ Amọri
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, to tun jẹ Minisita fun eto irinna lorileede wa, Rotimi Amaechi ti juwọ silẹ ninu erongba rẹ lati kopa ninu eto idibo abẹle lati dupo aarẹ. Oludari eto ipolongo ibo fun igbakeji Aarẹ, Sẹnetọ Kabiru Gaya, lo sọ eleyii di mimọ niluu Abuja lasiko to n ba ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels sọrọ.
Eyi waye lẹyin ipade ti awọn gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC lati ilẹ Yoruba ṣe lati ri i pe wọn fa ẹni kan ṣoṣo kalẹ fun idibo abẹle naa.
Ṣugbọn pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, o ti foju han bayii pe Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ati Aṣiwaju Bọla Tinubu ni wọn yoo jọ dupo naa, ti awọn mejeeji si wa lati iha Guusu, ti wọn tun jẹ ẹya Yoruba.
Ko sẹni to ti i le sọ boya ifikunlukun mi-in yoo tun waye, nibi ti kan ninu, ti yoo si ku ẹyọ ẹni kan pere.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: