Faith Adebọla
Akanda ẹda ni ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan ti wọn forukọ bo laṣiiri yii, o riran, o si n sọrọ, amọ o ni ipenija eti, odi ni, ko gbọrọ taara, pẹlu rẹ naa, awọn afurasi ọdaran meji yii, Aminu Hashimu, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati ọrẹ ẹ, Lukman Dogara, ẹni ọdun mejidinlogun, ko ro ti ipo tọmọbinrin naa wa rara, niṣẹ ni wọn dọgbọn tan an wọle, ti wọn si fipa ba a laṣepọ gidi, amọ ọwọ ti ba wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, DSP Ramhan Nansel, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan sọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta yii, pe, ọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn afurasi naa huwa ọdaju buruku naa.
O ni ile kan naa lawọn mejeeji n gbe, Opopona Owolosho, nijọba ibilẹ Obi, nipinlẹ Nasarawa, nile wọn wa, amọ ọtọ nile ti ọmọbinrin ti wọn ṣe ‘kinni’ fun lọran-an-yan naa n gbe, bo tilẹ jẹ pe adugbo kan naa ni.
O ni ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aṣalẹ lawọn eeyan ọmọbinrin naa tẹle e waa fẹjọ sun ni tọlọpaa pe awọn afurasi kan ti ṣi ọmọ awọn laṣọ wo, wọn si ti ṣe e yankan-yankan lodi si ifẹ inu ẹ.
Rahman ni bawọn ti gbọ sọrọ yii lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ si i dọdẹ awọn afurasi ọdaran ọhun, tori bi wọn ṣe ṣeṣekuṣe naa tan ni wọn ti na papa bora. Amọ lọjọ keji, wọn ri wọn mu, ijọba ibilẹ Obi ni wọn ti gan ọkan lapa, ijọba ibilẹ Lafia ti ekeji sa lọ ni wọn ti lọọ fofin mu un.
Iwadii tawọn ọlọpaa ṣe fi han pe ile kan to wa ni Opopona Okpe, nijọba ibilẹ Obi yii ni wọn tan ọmọbinrin naa lọ, nigba to wọle ni wọn ki i mọlẹ, ti wọn si tẹ ifẹkufẹẹ ọkan wọn lọrun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Maiyaki Baba, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ ṣayẹwo iṣegun fọmọbinrin ọhun lorukọ ijọba, ki wọn le fun un ni itọju to yẹ, bẹẹ lo ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ maa ba iwadii wọn niṣo. O lawọn afurasi naa maa too bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.