Jide Alabi
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ṣe ikojade ẹṣọ alaabo Amọtẹkun.
Nigba to n sọrọ nibi eto naa to waye nileewe awọn olukọni to wa niluu Ọyọ, Emmanuel Alayande College of Education, lo ti ṣe ikojade ẹgbẹrun kan ataabọ awọn ikọ Amọtekun naa leyin ti wọn ti fi odidi ọsẹ meji da wọn lẹkọọ lori iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ ọhun.
Gomina Makinde ni oun paṣẹ ikojade awọn ikọ naa lati maa mojuto eto aabo atawọn iwa to lodi sofin mi-in to le pa araalu lara nipinlẹ Ọyọ.
Makinde rọ awọn eeyan naa lati fi iwa ọmọluabi ṣiṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ. Beẹ lo fi kun un pe kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ ati ijọba ibilẹ onidagbasoke to wa nipinlẹ Ọyọ ni ikọ naa yoo ti maa mojuto eto aabo, ti wọn yoo si maa yide kiri lọsan-an ati lalẹ.