Amọtẹkun bẹrẹ idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ tuntun l’Ondo

 Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ idanilẹkọọ olosu kan fun awọn eeyan bii ẹgbẹta ti wọn ṣẹṣẹ gba wọle gẹgẹ bii oṣiṣẹ tuntun.

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ ninu ọrọ apilẹkọ rẹ lasiko ayẹyẹ iside idanilẹkọọ ọhun, eyi to waye ninu ọgba ileewe ẹkọṣẹ-ọwọ to wa niluu Ọwọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni awọn eeyan bii ẹgbẹrun mẹrinla ataabọ (14,500) ni wọn fifẹ han lati jẹ oṣiṣẹ awọn, ṣugbọn to jẹ pe ẹgbẹta pere lo yege ọkan-o-jọkan ayẹwo ti awọn ṣe fun wọn.

O ni lara ẹkọ tawọn oṣiṣẹ tuntun naa fẹẹ gba ni bi wọn ṣe n fimu finlẹ, bi wọn ṣe n ṣamulo nnkan ija, bi wọn ṣe n pẹtu saawọ ati ohunkohun to jẹ mọ eto aabo.

Oloye Adelẹyẹ kilọ fawọn eeyan naa lati sọra ṣe, ki wọn si gbiyanju lati tẹle gbogbo ofin ati ilana to rọ mọ igbekalẹ ẹsọ Amọtẹkun nitori pe iṣẹ naa ki i ṣeyi ti wọn yoo fi maa jẹ gaba tabi yan awọn araalu jẹ.

Awọn ti wọn ṣẹṣẹ gba ọhun la gbọ pe wọn wa lati inu ẹgbẹ OPC, Fijilante, ọdẹ atawọn ajijagbara mi-in kaakiri ipinlẹ Ondo.

 

Leave a Reply