Amọtẹkun fija pẹẹta pẹlu awọn janduku n’Ibadan, eeyan mẹrin lo dero ọrun

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan mẹrin ni wọn yinbọn pa laduugbo Lalábíran, n’Ibadan, ninu ija ibọn ati oogun abẹnu-gọngọ to waye laarin awọn ọmọ iṣọta agbegbe náà pẹlu awọn ẹṣọ Amọtẹkun.

Àdúgbo Labiran yii lo n gbona janjan lẹnu ọjọ mẹta yii, nitori bi awọn janduku ṣe n fi ojoojumọ kọ lu awọn araadugbo naa, ti wọn sì máa n ja wọn lole t’ọsan-t’oru.

Laarin oru Ọjọbọ, Tọsidee, sí aarọ ọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, ọpọlọpọ ile ati  mọto lawọn tọọgi náà dana sun.

Ninu ikọlu ti wọn tun ṣe sí àdúgbò yìí loru mọju leeyan mẹrin ti ku, nigba ti awọn oṣiṣẹ ẹṣọ Amọtẹkun lọọ koju wọn.

Ọkan ninu awọn ọdọ àdúgbò Labiran fìdí ẹ mulẹ pe “Awa gan-an ko wulẹ sun mọ́ lẹnu ọjọ mẹta yii, niṣe la n ṣọdẹ yika gbogbo adugbo wa ko ma di pe àwọn wèrè yẹn yoo lo oore ọfẹ ikọlu wọn láti máa fi jale.

“Ọkan ninu wa lo pe awọn Amọtẹkun lati waa ran wa lọwọ nigba ti awọn eeyan yẹn dé. Bi awọn Amọtẹkun ṣe dé ni wọn n yinbọn soke kẹ̀ù! kẹ̀ù! Bẹẹ lawọn tọọgi naa n yinbọn.

“Mẹrin ninu awọn tọọgi yẹn ti wọn n jẹ Monsuru, Ridwan pẹlu awọn meji mi-in lawọn Amọtẹkun pa.”

ALAROYE gbọ pe wọn ti sìnkú awọn ọdọkunrin naa laaarọ ọjọ Abamẹta.

Bó ṣe di nnkan bíi aago meji ọsan yii lọrọ tun di bó-ò-lọ-yàgò, nigba ti awọn ọmọ iṣọta wọnyi ti wọn ko din ni ọgọ́rùn-ún (100) niye tun gbàjọba oju popo gbogbo ladugbo Labiran yíi kan naa.

Bo tilẹ jẹ pé lọgan lawọn Amọtẹkun dé sibẹ láti pana laasigbo ọhun, ṣugbọn ọgbọọgbọn ti agbalagba fi í sá fún maaluu la gbọ pe wọn fi sa kuro nibẹ nitori pe awọn ẹruuku naa pọ jù wọn lọ.

Ṣugbọn laipẹ lawọn oṣiṣẹ eleto aabo naa pada de lakọtun pẹlu awọn agbofinro min-in bíi ọlọpaa ati Operation Burst, nigba naa lawọn alájààgbilà naa tóo juba ehoro.

Pẹlu ibẹru bojo lawọn ara Labiran fi n gbe bayii, awọn ti ọkàn wọn ko sí fi bẹẹ le ti fi adugbo naa silẹ lọọ fi ibomi-in ṣebugbe.

Leave a Reply