Amọtẹkun le awọn Fulani darandaran kuro nipinlẹ Ọyọ

 

Jide Alabi

Lati fopin si wahala tawọn janduku Fulani darandaran n ko ba awọn eeyan nipinlẹ Ọyọ ati agbegbe ẹ, awọn ẹṣọ Amọtẹkun atawọn ọlọdẹ ti ṣawari awọn kan ti wọn n fara pamọ sinu igbo, bẹẹ ni wọn ti le wọn kuro nipinlẹ ọhun bayii.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ni alaga ẹṣọ Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Ọgagun Kunle Togun sọrọ yii, eyi ti agbẹnusọ fun awọn ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Ayọlọla Adedọja, fi sita. O ni ninu igbo kan ti ijọba ya sọtọ, ti wọn pe ni Opara Forest Reserve, ati omi-in toun naa jẹ ibi ti ipinlẹ Ọyọ ya sọtọ fun iṣẹ agbẹ lọwọ ti tẹ awọn eeyan yii.

Wọn ni nigba ti ọwọ tẹ wọn, alaye tawọn Fulani darandaran yii ṣe ni pe awọn baalẹ kan lagbegbe ọhun lo kọwe ranṣẹ sawọn. Bo tilẹ jẹ pe wọn fa iwe ọhun yọ sawọn ẹṣọ yii, sibẹ, wọn ti sin wọn kuro nipinlẹ naa.

Togun dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ ọhun, bẹẹ lo rọ awọn araalu lati ni suuru fun awọn ẹṣọ yii, ki wọn le ṣaṣeyọri lori ọrọ aabo ti wọn gbe lọwọ.

Ọgagun yii dupẹ lọwọ awọn ọlọdẹ, eyi ti Ojiṣẹ Ọlọrun Ojuawo jẹ olori wọn, bakan naa lo dupẹ lori iranlọwọ ti ẹṣọ ọhun ri. O fi kun un pe inu oun yoo dun daadaaa ti wọn ba tun le fun awọn ni atilẹyin to dara si i.

Toogun fi kun ọrọ ẹ pe anafaani wa daadaa fun araalu lati sọrọ ti wọn ba ti ri awọn ibi to ku si nipa ẹṣọ Amọtẹkun, ṣugbọn ki wọn ma ṣe ṣatako to le da nnkan ru fun ẹṣọ ọhun.

Ọjọ kẹrinlelogun ọṣu kejila ni wọn kofiri awọn Fulani darandaran kan ni inu igbo kan ti wọn pe ni Opara Forest Reserve ni Oke Ogun, nipinlẹ Ọyọ. Lojuẹsẹ ni wọn fọrọ ọhun to alaga  fun awọn ẹṣọ Amọtẹkun leti, ti awọn ikọ wọn si gbe igbesẹ lojuẹsẹ.

Ni deede aago meji oru lọwọ tẹ awọn eeyan yii pẹlu iranlọwọ awọn ọlọdẹ, ti Ojiṣẹ Ọlọrun Ojoawo, jẹ olori wọn.

Awọn ọlọdẹ bii ogoji ni wọn jọ ṣiṣẹ yii, ti wọn si ko awọn Fulani yii kuro ni agbegbe Ṣaki, nijọba ibilẹ Oorelope, nipinlẹ Ọyọ.

Awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wọn wa nijọba ibilẹ Oorelope lawọn ọlọdẹ yii ko awọn Fulani darandaran yii fun, bẹẹ lawọn naa fa wọn le awọn eeyan wọn to wa ni Ọlọrunṣogo,  niluu Igbẹti, lọwọ, ti awọn yẹn si ri i pe wọn sin wọn jade kuro nipinlẹ Ọyọ.

Wọn ni ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fawọn ti ọwọ tẹ yii ni wọn ti sọ pe awọn baalẹ kan lo ni ki awọn wa, bẹẹ ni wọn mu lẹta ti wọn fun wọn jade pẹlu, ki wọn too sin wọn jade kuro nipinlẹ Ọyọ.

 

Leave a Reply