Amọtẹkun mu awọn Fulani mọkanlelogun ti wọn sa pamọ sinu tirela l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn Hausa/Fulani ti wọn to mọkanlelogun lagbegbe Isọ-Pako, loju ọna Ondo, niluu Ileefẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ọkada ni wọn ko sinu mọto tirela to gbe wọn de agbegbe naa, ti ko si sẹni to mọ pe awọn eeyan yii wa labẹ ọkada, afi igba ti awọn Amọtẹkun da wọn duro.

Gẹgẹ bi alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣe sọ, nigba ti awọn Amọtẹkun ri i pe ọkada lasan lawọn n wo ninu tirela naa lo jẹ ki wọn dọdẹ wọn titi de agbegbe Ajebamdele ọhun.

Nigba ti wọn da awakọ tirela naa duro, ti wọn ni ko ṣi ẹyin rẹ ni wọn ba awọn ọdọkunrin mọkanlelogun nibẹ.

Amitolu fi kun ọrọ rẹ pe wọn beere ibi ti wọn n lọ, ṣugbọn wọn ko le sọ ni pato ibi kankan, awọn miiran si n sọ laarin wọn pe ipinlẹ Zamfara lawọn n lọ.

O ni awọn ti fa wọn le awọn agbofinro ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran niluu Oṣogbo lọwọ fun iwadi.

A oo ranti pe laipẹ yii nijọba ipinlẹ Ọṣun kegbajare pe awọn ọdaran kan ti n fi ọkada ati korope huwa buburu kaakiri ipinlẹ Oṣun, ti wọn si sọ pe ki awọn araalu joye oju-lalakan-fi-n-ṣọri.

Leave a Reply