Amọtẹkun tẹ Afeez ati ọrẹ rẹ ti wọn fipa ba ọmọbinrin to n ṣe nnkan oṣu lo pọ n’Iwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọdọmọkunrin meji kan, Adegoroye Afeez, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Ọlamilekan Elijah, ẹni ọdun mẹtalelogun, ti ko sakolo ikọ Amọtẹkun lori ẹsun pe wọn fipa ba ọdọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun lo pọ.
Gẹgẹ bi Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣe sọ fun Alaroye, koko (Cocoa merchants) lawọn afurasi mejeeji yii niluu Iwo, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn huwa buburu naa.
Yatọ si pe wọn fipa ba ọmọbinrin naa lo pọ, wọn tun ṣe fidio ifipabanilopọ naa sori foonu ọkan lara wọn, awọn mejeeji ni wọn si jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Alora lawọn, ṣugbọn ofin ẹgbẹ awọn koro oju si iwa ifipabanilopọ.
Ninu ọrọ tirẹ, Afeez ṣalaye pe loootọ loun ti niyawo, ti oun si ti bimọ, ṣugbọn ọrẹbinrin oun ni ọmọbinrin naa. O ni nigba ti oun sọ fun un pe kawọn jọ ni ibaṣepọ lọjọ naa, ko fẹẹ gba, loun ṣe pinnu lato fipa ba a lo pọ.
Afeez fi kun ọrọ rẹ pe loootọ ni ọmọ naa sọ fun oun pe oun n ṣe nnkan-oṣu lọwọ, ṣugbọn nigba ti oun wo paadi (Pad) to wa labẹ rẹ, oun ko ri ẹjẹ kankan nibẹ.

O sọ siwaju pe oun nikan loun fipa ba a lo pọ, ṣe ni ọrẹ oun kan n ya fidio bi oun ṣe n ṣe e. O ni Poli Igbajọ loun ti darapọ mọ ẹgbẹ okunkun Alora, ṣugbọn awọn ki i huwa ika, iṣẹ aanu lawọn maa n ṣe ninu ẹgbẹ naa.
Ni ti Ọlamilekan, o ni ilu Iwo loun ti darapọ mọ ẹgbẹ okunkun Alora ni toun, ṣe lawọn si maa n dawo lati fi ra nnkan lọ sile awọn ọmọ alainiyaa.
Lọjọ iṣẹlẹ yii, o ni oun loun ba Afeez ati ọrẹbinrin rẹ tan jẹnẹretọ, ti oun si tan redio, o ni nigba to n ṣagidi lasiko ti Afeez fẹẹ ba a lajọṣepọ loun di i lọwọ mu, ti oun si fidio rẹ.
Awọn mejeeji ni wọn sọ pe awọn kabaamọ iwa ti awọn hu, nitori awọn ko mọ iru ijiya to n duro de awọn ninu ẹgbẹ Alora ti awọn wa.
Amitolu waa gboriyin fun Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, fun anfaani to fun ajọ Amọtẹkun lati ṣiṣẹ nipasẹ eyi ti iwa ọdran fi n dinku nipinlẹ Ọṣun, o ni ibaṣepọ to dan mọnran lo wa laarin ajọ naa ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ.

Leave a Reply